Gẹn 5:15-32
Gẹn 5:15-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi: Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Mahalaleli si jẹ ẹ̃dẹgbẹ̀run ọdún o dí marun: o si kú. Jaredi si wà li ọgọjọ ọdún o lé meji, o si bí Enoku: Jaredi si wà li ẹgbẹrin ọdún lẹhin igbati o bì Enoku, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Jaredi si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mejidilogoji: o si kú. Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela: Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji: Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki: Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú. Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan: O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú. Lameki si wà li ẹgbẹta ọdún o dí marun, lẹhin ti o bí Noa, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Lameki si jẹ ẹgbẹrin ọdún o dí mẹtalelogun: o si kú. Noa si jẹ ẹni ẹ̃dẹgbẹta ọdún: Noa si bí Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.
Gẹn 5:15-32 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi. Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú. Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku. Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú. Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365). Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ. Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki. Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Metusela gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mọkandinlaadọrin (969) kí ó tó kú. Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.” Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú. Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti.
Gẹn 5:15-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Jaredi. Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú. Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Enoku. Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dínméjìdínlógójì (962), ó sì kú. Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Metusela. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irínwó-dínmárùn-dínlógójì-ọdún (365). Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ. Nígbà tí Metusela pé igba ó-dínmẹ́tàlá ọdún (187) ní o bí Lameki. Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rìn-dínméjì-dínlógún ọdún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó-dínmọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú. Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn ún.” Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ó-dínmárùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún ó-dínmẹ́tàlélógún (777), ó sì kú. Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.