Gẹn 49:1-33
Gẹn 49:1-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
JAKOBU si pè awọn ọmọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ kó ara nyin jọ, ki emi ki o le wi ohun ti yio bá nyin lẹhin-ọla fun nyin. Ẹ kó ara nyin jọ, ki ẹ si gbọ́, ẹnyin ọmọ Jakobu; ki ẹ si fetisi ti Israeli baba nyin. Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara. Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi. Simeoni on Lefi, arakunrin ni nwọn; ohun-èlo ìka ni idà wọn. Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì. Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli. Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ. Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide? Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀. Yio ma so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ ara àjara, ati ọmọ kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ mọ́ ara ãyo àjara; o ti fọ̀ ẹ̀wu rẹ̀ ninu ọtí-waini, ati aṣọ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ eso àjara: Oju rẹ̀ yio pọ́n fun ọtí-waini, ehín rẹ̀ yio si funfun fun wàra. Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni. Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan. O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú. Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli. Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin. Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA! Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn. Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá. Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere. Josefu li ẹka eleso pupọ̀, ẹka eleso pupọ̀ li ẹba kanga; ẹtun ẹniti o yọ si ori ogiri. Awọn tafàtafa bà a ninu jẹ́ pọ̀ju, nwọn si tafà si i, nwọn si korira rẹ̀: Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,) Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu. Ibukún baba rẹ ti jù ibukún awọn baba nla mi lọ, titi dé opin oke aiyeraiye wọnni: nwọn o si ma gbé ori Josefu, ati li atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. Benjamini ni yio ma fàniya bi ikõkò: ni kutukutu ni yio ma jẹ ẹran-ọdẹ rẹ̀, ati li aṣalẹ ni yio ma pín ikogun rẹ̀. Gbogbo wọnyi li awọn ẹ̀ya Israeli mejejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukún tirẹ̀, li o sure fun wọn. O si kìlọ fun wọn, o si sọ fun wọn pe, A o kó mi jọ pọ̀ pẹlu awọn enia mi: ẹ sin mi pẹlu awọn baba mi ni ihò ti o mbẹ li oko Efroni ara Hitti. Ninu ihò ti o mbẹ ninu oko Makpela ti mbẹ niwaju Mamre, ni ilẹ Kenaani, ti Abrahamu rà pẹlu oko lọwọ Efroni, ara Hitti fun ilẹ-isinku. Nibẹ̀ ni nwọn sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀; nibẹ̀ ni nwọn sin Isaaki ati Rebeka aya rẹ̀; nibẹ̀ ni mo si sin Lea: Lọwọ awọn ọmọ Heti li a ti rà oko na ti on ti ihò ti o wà nibẹ̀. Nigbati Jakobu si ti pari aṣẹ ipa fun awọn ọmọ rẹ̀, o kó ẹsẹ̀ rẹ̀ jọ sori akete, o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.
Gẹn 49:1-33 Yoruba Bible (YCE)
Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín. Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín. Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi, ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ, tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi. Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn, o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀, o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́. Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin, ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn. Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀, ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́. Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan, wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá. Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le, ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n. N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu, n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli. Juda, àwọn arakunrin rẹ yóo máa yìn ọ́, apá rẹ yóo sì ká àwọn ọ̀tá rẹ; àwọn ọmọ baba rẹ yóo máa tẹríba fún ọ. Juda dàbí kinniun, tí ó bá pa ohun tí ó ń dọdẹ tán, a sì tún yan pada sinu ihò rẹ̀. Tí ó bá nà kalẹ̀, tí ó sì lúgọ, kò sí ẹni tí ó jẹ́ tọ́ ọ. Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Yóo máa so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà, yóo so àwọ́nsìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́ ìtàkùn àjàrà dáradára, bẹ́ẹ̀ ni oje àjàrà ni yóo máa fi fọ ẹ̀wù rẹ̀. Ojú rẹ̀ yóo pọ́n fún àmutẹ́rùn ọtí waini, eyín rẹ̀ yóo sì funfun fún àmutẹ́rùn omi wàrà. “Sebuluni yóo máa gbé etí òkun, ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ kò ní níye, Sidoni ni yóo jẹ́ ààlà rẹ̀. “Isakari dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó lágbára tí ó dùbúlẹ̀ láàrin gàárì ẹrù rẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé ibi ìsinmi dára ati pé ilẹ̀ náà dára, ó tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ láti ru ẹrù, ó sì di ẹni tí wọn ń mú sìn bí ẹrú. Dani ni yóo máa ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dani yóo dàbí ejò lójú ọ̀nà, ati bíi paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ń bu ẹṣin ní gìgísẹ̀ jẹ, kí ẹni tí ó gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn. Mo dúró de ìgbàlà rẹ, Oluwa. Àwọn olè yóo máa kó Gadi lẹ́rù, ṣugbọn bí wọ́n ti ń kó o, bẹ́ẹ̀ ni yóo sì máa gbà á pada. Aṣeri yóo máa rí oúnjẹ dáradára mú jáde ninu oko rẹ̀, oúnjẹ ọlọ́lá ni yóo máa ti inú oko rẹ̀ jáde. Nafutali dàbí àgbọ̀nrín tí ń sáré káàkiri, tí ó sì ní àwọn ọmọ tí ó lẹ́wà. Josẹfu dàbí igi eléso tí ó wà lẹ́bàá odò, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà mọ́ ara ògiri. Àwọn tafàtafà gbógun tì í kíkankíkan, wọ́n ń ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dà á láàmú gidigidi, sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì, apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i. Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun, (ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà, tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli), Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá, yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Ibukun àwọn baba rẹ ju ti àwọn òkè ayérayé lọ, kí ibukun àwọn òkè ayérayé wá sórí Josẹfu, ẹni tí wọ́n yà ní ipá lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀. “Bẹnjamini dàbí ìkookò tí ebi ń pa, a máa pa ohun ọdẹ rẹ̀ ní òwúrọ̀, ati ní àṣáálẹ́ a máa pín ìkógun rẹ̀.” Àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni a ti dárúkọ yìí, ati ohun tí baba wọn wí nígbà tí ó súre fún wọn. Ó súre tí ó tọ́ sí olukuluku fún un. Jakọbu kìlọ̀ fún wọn, ó ní, “Mo ṣetán, mò ń re ibi àgbà á rè, inú ibojì tí wọ́n sin àwọn baba mi sí, ninu ihò òkúta tí ó wà ninu ilẹ̀ Efuroni, ará Hiti, ni kí ẹ sin mí sí. Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú. Níbẹ̀ ni wọ́n sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni wọ́n sin Isaaki sí ati Rebeka aya rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi náà sì sin Lea sí. Lọ́wọ́ àwọn ará Hiti ni wọ́n ti ra ilẹ̀ náà ati ihò òkúta tí ó wà ninu rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ sin mí sí.” Nígbà tí Jakọbu parí ìkìlọ̀ tí ó ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ pada sí orí ibùsùn rẹ̀, ó dùbúlẹ̀, lẹ́yìn náà ó mí kanlẹ̀, ó sì re ibi tí àgbà á rè.
Gẹn 49:1-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín. “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu; Ẹ fetí sí Israẹli baba yín. “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi, agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi, títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára. Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀). “Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin— idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára. Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n. Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀, àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà. Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu, èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli. “Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ, ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ. Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda, o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi. Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún, Ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde? Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Juda bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé, tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un. Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà, àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù. Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì àti ẹ̀wù rẹ̀ nù nínú omi-pupa ti èso àjàrà (gireepu). Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ, eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ. “Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun, yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi, agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni. “Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbára tí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn. Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó, àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó, yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà, yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá. “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn. “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, OLúWA. “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi, ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn. “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára; yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba. “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nrín tí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára. “Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso, àjàrà eléso ní etí odò, tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi. Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́, wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra, Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu, nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli, nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọ pẹ̀lú láti ọ̀run wá, ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀, ìbùkún ti ọmú àti ti inú. Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì, ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé. Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu, lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀. “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú; ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ, ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.” Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i. Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.” Nígbà tí Jakọbu ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.