Gẹn 47:1-31

Gẹn 47:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Josẹfu bá wọlé lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi ati àwọn arakunrin mi ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, pẹlu gbogbo agbo ẹran ati agbo mààlúù wọn, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní, wọ́n sì wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” Ó mú marun-un ninu àwọn arakunrin rẹ̀, ó fi wọ́n han Farao. Farao bi àwọn arakunrin rẹ̀ léèrè irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n dá Farao lóhùn pé, darandaran ni àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn. Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni. Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Ọ̀dọ̀ rẹ ni baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ wá. Wo ilẹ̀ Ijipti láti òkè dé ilẹ̀, ibikíbi tí o bá rí i pé ó dára jùlọ ninu gbogbo ilẹ̀ náà ni kí o fi baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ sí. Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, bí o bá sì mọ èyíkéyìí ninu wọn tí ó lè bojútó àwọn ẹran ọ̀sìn dáradára, fi ṣe alabojuto àwọn ẹran ọ̀sìn mi.” Josẹfu bá mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé láti fihan Farao, Jakọbu sì súre fún Farao. Farao bi Jakọbu pé, “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́ báyìí?” Jakọbu dá a lóhùn pé, “Ọjọ́ orí mi jẹ́ aadoje (130) ọdún. Ọjọ́ orí mi kò tó nǹkan rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti rí ọpọlọpọ ibi. Ọjọ́ orí mi kò tíì dé ibìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn baba mi.” Jakọbu súre fún Farao ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ. Josẹfu pèsè ohun jíjẹ fún baba ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí olukuluku wọn ń bọ́. Ìyàn náà mú tóbẹ́ẹ̀ tí ìdààmú bá gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani nítorí pé kò sí oúnjẹ rárá ní ilẹ̀ Kenaani. Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao. Nígbà tí kò sí owó mọ́ rárá ní ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani, gbogbo àwọn ará Ijipti tọ Josẹfu lọ, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran báyìí títí tí a óo fi kú? Kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá.” Josẹfu bá dá wọn lóhùn pé, “Bí kò bá sí owó lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ kó àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, n óo sì fun yín ní oúnjẹ dípò wọn.” Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà. Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.” Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao, ó sì sọ àwọn eniyan náà di ẹrú rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn. Josẹfu sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Àtẹ̀yin, àtilẹ̀ yín, láti òní lọ, mo ra gbogbo yín fún Farao. Irúgbìn nìyí, ẹ lọ gbìn ín sinu oko yín. Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.” Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.” Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao. Israẹli ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ní Goṣeni, wọ́n sì ní ọpọlọpọ ohun ìní níbẹ̀, wọ́n bímọ lémọ, wọ́n sì pọ̀ sí i gidigidi. Ọdún mẹtadinlogun ni Jakọbu gbé sí i ní ilẹ̀ Ijipti, gbogbo ọdún tí ó gbé láyé sì jẹ́ ọdún mẹtadinlaadọjọ (147). Nígbà tí àkókò tí Jakọbu yóo kú súnmọ́ tòsí, ó pe Josẹfu ọmọ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Wá, ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, kí o sì ṣèlérí pé o óo ṣe olóòótọ́ sí mi, o kò sì ní dà mí. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.” Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.” Jakọbu ní kí Josẹfu búra fún òun, Josẹfu sì búra fún un. Nígbà náà ni Jakọbu tẹríba lórí ibùsùn rẹ̀.

Gẹn 47:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Josefu wọle, o si sọ fun Farao, o si wipe, Baba mi, ati awọn arakunrin mi ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, nwọn ti ilẹ Kenaani wá; si kiyesi i, nwọn mbẹ ni ilẹ Goṣeni. O si mú marun ninu awọn arakunrin rẹ̀, o si mu wọn duro niwaju Farao. Farao si bi awọn arakunrin rẹ̀ pe, Kini iṣẹ nyin? Nwọn si wi fun Farao pe, Oluṣọ-agutan li awọn iranṣẹ rẹ, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu. Nwọn si wi fun Farao pẹlu pe, Nitori ati ṣe atipo ni ilẹ yi li awa ṣe wá; nitori awọn iranṣẹ rẹ kò ní papa-oko tutù fun ọwọ́-ẹran wọn; nitori ti ìyan yi mú gidigidi ni ilẹ Kenaani: njẹ nitorina awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awọn iranṣẹ rẹ ki o joko ni ilẹ Goṣeni. Farao si wi fun Josefu pe, Baba rẹ ati awọn arakunrin rẹ tọ̀ ọ wá: Ilẹ Egipti ni yi niwaju rẹ; ninu ãyo ilẹ ni ki o mu baba ati awọn arakunrin rẹ joko; jẹ ki nwọn ki o joko ni ilẹ Goṣeni: bi iwọ ba si mọ̀ ẹnikẹni ti o li ãpọn ninu wọn, njẹ ki iwọ ki o ṣe wọn li olori lori ẹran-ọsin mi. Josefu si mú Jakobu baba rẹ̀ wọle wá, o si mu u duro niwaju Farao: Jakobu si sure fun Farao. Farao si bi Jakobu pe, Ọdún melo li ọjọ́ aiye rẹ? Jakobu si wi fun Farao pe, Ãdoje ọdún li ọjọ́ atipo mi: diẹ ti on ti buburu li ọdún ọjọ́ aiye mi jẹ́, nwọn kò si ti idé ọdún ọjọ́ aiye awọn baba mi li ọjọ́ atipo wọn. Jakobu si sure fun Farao, o si jade kuro niwaju Farao. Josefu si fi baba rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ joko, o si fun wọn ni iní ni ilẹ Egipti, ni ibi ãyo ilẹ, ni ilẹ Ramesesi, bi Farao ti pa li aṣẹ. Josefu si fi onjẹ bọ́ baba rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ile baba rẹ̀ gẹgẹ bi iye awọn ọmọ wọn. Onjẹ kò si sí ni gbogbo ilẹ; nitori ti ìyan na mú gidigidi, tobẹ̃ ti ilẹ Egipti ati gbogbo ilẹ Kenaani gbẹ nitori ìyan na. Josefu si kó gbogbo owo ti a ri ni ilẹ Egipti ati ni ilẹ Kenaani jọ, fun ọkà ti nwọn rà: Josefu si kó owo na wá si ile Farao. Nigbati owo si tán ni ilẹ Egipti, ati ni ilẹ Kenaani, gbogbo awọn ara Egipti tọ̀ Josefu wá, nwọn si wipe, Fun wa li onjẹ: nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ? owo sa tán. Josefu si wipe, Ẹ mú ẹran nyin wá, emi o si fun nyin li onjẹ dipò ẹran nyin, bi owo ba tán. Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na. Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa: Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro. Bẹ̃ni Josefu rà gbogbo ilẹ Egipti fun Farao; nitori olukuluku awọn ara Egipti li o tà oko rẹ̀, nitori ti ìyan na mú wọn: ilẹ si di ti Farao. Bi o si ṣe ti awọn enia ni, o ṣí wọn si ilu, lati opin ilẹ kan ni Egipti dé opin ilẹ keji. Kìki ilẹ awọn alufa ni kò rà; nitori ti awọn alufa ní ipín ti wọn lati ọwọ́ Farao wá, nwọn si njẹ ipín wọn ti Farao fi fun wọn; nitorina ni nwọn kò fi tà ilẹ wọn. Nigbana ni Josefu wi fun awọn enia pe, Kiyesi i, emi ti rà nyin loni ati ilẹ nyin fun Farao: wò o, irugbìn niyi fun nyin, ki ẹnyin ki o si gbìn ilẹ na. Yio si se, ni ikore ki ẹnyin ki o fi ida-marun fun Farao, ọ̀na mẹrin yio jẹ́ ti ara nyin fun irugbìn oko, ati fun onjẹ nyin, ati fun awọn ara ile nyin, ati onjẹ fun awọn ọmọ nyin wẹrẹ. Nwọn si wipe, Iwọ ti gbà ẹmi wa là: ki awa ki o ri ore-ọfẹ li oju oluwa mi, awa o si ma ṣe ẹrú Farao. Josefu si ṣe e ni ilana ni ilẹ Egipti titi di oni-oloni pe, Farao ni yio ma ní idamarun; bikoṣe ilẹ awọn alufa nikan ni kò di ti Farao. Israeli si joko ni ilẹ Egipti, ni ilẹ Goṣeni; nwọn si ní iní nibẹ̀, nwọn bísi i, nwọn si rẹ̀ gidigidi. Jakobu si wà li ọdún mẹtadilogun ni ilẹ Egipti; gbogbo ọjọ́ aiye Jakobu si jẹ́ ãdọjọ ọdún o di mẹta: Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti. Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi. O si wipe, Bura fun mi. On si bura fun u. Israeli si tẹriba lori akete.

Gẹn 47:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Josẹfu bá wọlé lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi ati àwọn arakunrin mi ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, pẹlu gbogbo agbo ẹran ati agbo mààlúù wọn, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní, wọ́n sì wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” Ó mú marun-un ninu àwọn arakunrin rẹ̀, ó fi wọ́n han Farao. Farao bi àwọn arakunrin rẹ̀ léèrè irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n dá Farao lóhùn pé, darandaran ni àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn. Wọ́n tún wí fún Farao pé, àwọn wá láti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ rẹ̀ ni, nítorí pé ìyàn ńlá tí ó mú ní ilẹ̀ Kenaani kò jẹ́ kí koríko wà fún àwọn ẹran àwọn. Wọ́n ní àwọn wá bẹ Farao ni, pé kí ó jẹ́ kí àwọn máa gbé ilẹ̀ Goṣeni. Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Ọ̀dọ̀ rẹ ni baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ wá. Wo ilẹ̀ Ijipti láti òkè dé ilẹ̀, ibikíbi tí o bá rí i pé ó dára jùlọ ninu gbogbo ilẹ̀ náà ni kí o fi baba rẹ ati àwọn arakunrin rẹ sí. Jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, bí o bá sì mọ èyíkéyìí ninu wọn tí ó lè bojútó àwọn ẹran ọ̀sìn dáradára, fi ṣe alabojuto àwọn ẹran ọ̀sìn mi.” Josẹfu bá mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé láti fihan Farao, Jakọbu sì súre fún Farao. Farao bi Jakọbu pé, “Ẹni ọdún mélòó ni ọ́ báyìí?” Jakọbu dá a lóhùn pé, “Ọjọ́ orí mi jẹ́ aadoje (130) ọdún. Ọjọ́ orí mi kò tó nǹkan rárá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi ti rí ọpọlọpọ ibi. Ọjọ́ orí mi kò tíì dé ibìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn baba mi.” Jakọbu súre fún Farao ó sì jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ. Josẹfu pèsè ohun jíjẹ fún baba ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye eniyan tí olukuluku wọn ń bọ́. Ìyàn náà mú tóbẹ́ẹ̀ tí ìdààmú bá gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani nítorí pé kò sí oúnjẹ rárá ní ilẹ̀ Kenaani. Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao. Nígbà tí kò sí owó mọ́ rárá ní ilẹ̀ Ijipti ati ilẹ̀ Kenaani, gbogbo àwọn ará Ijipti tọ Josẹfu lọ, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran báyìí títí tí a óo fi kú? Kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá.” Josẹfu bá dá wọn lóhùn pé, “Bí kò bá sí owó lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ kó àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, n óo sì fun yín ní oúnjẹ dípò wọn.” Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà. Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa. Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.” Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao, ó sì sọ àwọn eniyan náà di ẹrú rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn. Josẹfu sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Àtẹ̀yin, àtilẹ̀ yín, láti òní lọ, mo ra gbogbo yín fún Farao. Irúgbìn nìyí, ẹ lọ gbìn ín sinu oko yín. Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.” Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.” Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao. Israẹli ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ní Goṣeni, wọ́n sì ní ọpọlọpọ ohun ìní níbẹ̀, wọ́n bímọ lémọ, wọ́n sì pọ̀ sí i gidigidi. Ọdún mẹtadinlogun ni Jakọbu gbé sí i ní ilẹ̀ Ijipti, gbogbo ọdún tí ó gbé láyé sì jẹ́ ọdún mẹtadinlaadọjọ (147). Nígbà tí àkókò tí Jakọbu yóo kú súnmọ́ tòsí, ó pe Josẹfu ọmọ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Wá, ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, kí o sì ṣèlérí pé o óo ṣe olóòótọ́ sí mi, o kò sì ní dà mí. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.” Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.” Jakọbu ní kí Josẹfu búra fún òun, Josẹfu sì búra fún un. Nígbà náà ni Jakọbu tẹríba lórí ibùsùn rẹ̀.

Gẹn 47:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Josẹfu lọ sọ fún Farao pé, “Baba mi àti àwọn arákùnrin mi, pẹ̀lú agbo ẹran, agbo màlúù àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, ti dé láti ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Goṣeni báyìí.” Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Farao. Farao béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kí ni iṣẹ́ yín?” Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran” Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ohun ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má ṣàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni.” Farao wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá, Ilẹ̀ Ejibiti sì nìyí níwájú rẹ: Mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà. Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Goṣeni. Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran ọ̀sìn mi.” Nígbà náà ni Josẹfu mú Jakọbu baba rẹ̀ wọlé wá sí iwájú Farao. Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu súre fún Farao tán. Farao béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?” Jakọbu sì dá Farao lóhùn, “Ọdún ìrìnàjò ayé mi jẹ́ àádóje (130), ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, síbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi.” Nígbà náà ni Jakọbu tún súre fún Farao, ó sì jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀. Josẹfu sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Ejibiti, ó sì fún wọn ní ohun ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbègbè Ramesesi bí Farao ti pàṣẹ. Josẹfu sì pèsè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Ejibiti àti ilẹ̀ Kenaani gbẹ nítorí ìyàn náà. Josẹfu gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti àti Kenaani ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Farao. Nígbà tí owó wọn tán pátápátá ní Ejibiti àti Kenaani, gbogbo Ejibiti wá bá Josẹfu, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tán.” Josẹfu wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.” Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹṣin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn wọn. Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀lé, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tókù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa. Èéṣe tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkára wa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbèkùn Farao. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.” Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao, Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì Ṣùgbọ́n ṣá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Farao, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Farao ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn. Josẹfu wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ́n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Farao, irúgbìn rèé, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìre oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdákan nínú ìdámárùn-ún rẹ̀ fún Farao. Ẹ le pa ìdámẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.” Wọ́n dá á lóhùn pé, “O ti gbà wá là, Ǹjẹ́ kí a rí ojúrere níwájú olúwa wa, àwa yóò di ẹrú Farao.” Nítorí náà Josẹfu sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Ejibiti, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òní olónìí pé, ìdákan nínú ìdámárùn-ún ìre oko jẹ́ ti Farao, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Farao. Àwọn ará Israẹli sì tẹ̀dó sí Ejibiti ní agbègbè Goṣeni. Wọ́n ní ohun ìní fún ara wọn, wọ́n sì bí sí i tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n pọ̀ si gidigidi ní iye. Jakọbu gbé ní Ejibiti fún ọdún mẹ́tà-dínlógún (17) iye ọdún ọjọ́ ayé rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tàdín ní àádọ́jọ (147). Nígbà tí àkókò ń súnmọ́ etílé fún Israẹli láti kú, ó pe Josẹfu, ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Bí mo bá rí ojúrere ni ojú rẹ̀ fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, kí o sì ṣe ìlérí pé ìwọ yóò fi àánú àti òtítọ́ hàn sí mi. Má ṣe sin òkú mi sí ilẹ̀ Ejibiti, Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Ejibiti kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.” Josẹfu sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.” Jakọbu wí pé, “Búra fún mi,” Josẹfu sì búra fún un. Israẹli sì tẹ orí rẹ̀ ba, bí ó ti sinmi lé orí ibùsùn rẹ̀.