Gẹn 46:1-34
Gẹn 46:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
ISRAELI si mú ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n ti on ti ohun gbogbo ti o ní, o si dé Beer-ṣeba, o si rú ẹbọ si Ọlọrun Isaaki baba rẹ̀. Ọlọrun si bá Israeli sọ̀rọ li ojuran li oru, o si wipe, Jakobu, Jakobu. O si wipe, Emi niyi. O si wipe, Emi li Ọlọrun, Ọlọrun baba rẹ: má bẹ̀ru lati sọkalẹ lọ si ilẹ Egipti; nitori ibẹ̀ li emi o gbé sọ iwọ di orilẹ-ède nla. Emi o si bá ọ sọkalẹ lọ si Egipti; emi o si mú ọ goke wá nitõtọ: Josefu ni yio si fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọ li oju dé. Jakobu si dide lati Beer-ṣeba lọ: awọn ọmọ Israeli si mú Jakobu baba wọn lọ, ati awọn ọmọ wẹrẹ wọn, ati awọn aya wọn, ninu kẹkẹ́-ẹrù ti Farao rán lati mú u lọ. Nwọn si mú ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ti nwọn ní ni ilẹ Kenaani, nwọn si wá si Egipti, Jakobu, ati gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: Awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin awọn ọmọ rẹ̀, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ li o mú pẹlu rẹ̀ wá si ilẹ Egipti. Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti, Jakobu ati awọn ọmọ rẹ̀: Reubeni, akọ́bi Jakobu. Ati awọn ọmọ Reubeni; Hanoku, ati Pallu, ati Hesroni, ati Karmi. Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu, ọmọ obinrin ara Kenaani kan. Ati awọn ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari. Ati awọn ọmọ Judah; Eri ati Onani, ati Ṣela, ati Peresi, ati Sera: ṣugbọn Eri on Onani ti kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Peresi ni Hesroni on Hamulu. Ati awọn ọmọ Issakari; Tola, ati Pufa, ati Jobu, ati Simroni. Ati awọn ọmọ Sebuluni; Seredi, ati Eloni, ati Jaleeli. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Lea, ti o bí fun Jakobu ni Padan-aramu, pẹlu Dina ọmọbinrin rẹ̀: gbogbo ọkàn awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, o jẹ́ mẹtalelọgbọ̀n. Ati awọn ọmọ Gadi; Sifioni, ati Haggi, Ṣuni, ati Esboni, Eri, ati Arodi, ati Areli. Ati awọn ọmọ Aṣeri; Jimna, ati Iṣua, ati Isui, ati Beria, ati Sera arabinrin wọn: ati awọn ọmọ Beria; Heberi, ati Malkieli. Wọnyi li awọn ọmọ Silpa, ti Labani fi fun Lea ọmọbinrin rẹ̀, wọnyi li o si bí fun Jakobu, ọkàn mẹrindilogun. Awọn ọmọ Rakeli aya Jakobu; Josefu ati Benjamini. Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u. Ati awọn ọmọ Benjamini; Bela, ati Bekeri, ati Aṣbeli, Gera, ati Naamani, Ehi, ati Roṣi, Muppimu, ati Huppimu, ati Ardi. Wọnyi li awọn ọmọ Rakeli, ti a bí fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ mẹrinla. Ati awọn ọmọ Dani; Huṣimu. Ati awọn ọmọ Naftali; Jahseeli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣillemu. Wọnyi si li awọn ọmọ Bilha, ti Labani fi fun Rakeli ọmọbinrin rẹ̀, o si bí wọnyi fun Jakobu: gbogbo ọkàn na jẹ́ meje. Gbogbo ọkàn ti o ba Jakobu wá si Egipti, ti o si ti inu Jakobu jade, li àika aya awọn ọmọ Jakobu, ọkàn na gbogbo jẹ́ mẹrindilãdọrin; Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn. O si rán Judah siwaju rẹ̀ si Josefu ki o kọju wọn si Goṣeni; nwọn si dé ilẹ Goṣeni. Josefu si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si lọ si Goṣeni lọ ipade Israeli baba rẹ̀, o si fi ara rẹ̀ hàn a; on si rọ̀ mọ́ ọ li ọrùn, o si sọkun si i li ọrùn pẹ titi. Israeli si wi fun Josefu pe, Jẹ ki emi ki o kú wayi, bi mo ti ri oju rẹ yi, nitori ti iwọ wà lãye sibẹ̀. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀, ati fun awọn ara ile baba rẹ̀ pe, Emi o goke lọ, emi o si sọ fun Farao, emi o si wi fun u pe, Awọn arakunrin mi, ati awọn ara ile baba mi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, nwọn tọ̀ mi wá; Oluṣọ-agutan si li awọn ọkunrin na, ẹran sisìn ni iṣẹ wọn; nwọn si dà agbo-ẹran ati ọwọ́-ẹran wọn wá, ati ohun gbogbo ti nwọn ní. Yio si ṣe, nigbati Farao ba pè nyin, ti yio si bi nyin pe, Kini iṣẹ nyin? Ki ẹnyin ki o wipe, Òwo awọn iranṣẹ rẹ li ẹran sisìn lati ìgba ewe wa wá titi o fi di isisiyi, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu: ki ẹnyin ki o le joko ni ilẹ Goṣeni; nitori irira li oluṣọ-agutan gbogbo si awọn ara Egipti.
Gẹn 46:1-34 Yoruba Bible (YCE)
Israẹli di gbogbo ohun tí ó ní, ó kó lọ sí Beeriṣeba, ó lọ rúbọ sí Ọlọrun Isaaki, baba rẹ̀. Ọlọrun bá a sọ̀rọ̀ lójú ìran lóru, ó pè é, ó ní, “Jakọbu, Jakọbu.” Ó dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Ọlọrun wí pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, má fòyà rárá láti lọ sí Ijipti, nítorí pé n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. N óo bá ọ lọ sí Ijipti, n óo sì tún mú ọ pada wá, ọwọ́ Josẹfu ni o óo sì dákẹ́ sí.” Jakọbu bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Beeriṣeba. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé e sinu ọkọ̀ tí Farao fi ranṣẹ sí i pé kí wọ́n fi gbé e wá, wọ́n sì kó àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ pẹlu wọn. Wọ́n kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n lọ sí Ijipti. Gbogbo ilé rẹ̀ patapata ni Jakọbu kó lọ́wọ́ lọ sí Ijipti, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, gbogbo wọn ni ó kó lọ sí Ijipti patapata. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ Reubẹni wọnyi: Hanoku, Palu, Hesironi, ati Karimi. Àwọn ọmọ ti Simeoni ni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari, ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani bí fún un. Àwọn ọmọ ti Lefi ni: Geriṣoni, Kohati, ati Merari. Àwọn ọmọ ti Juda ni: Eri, Onani, Ṣela, Peresi, ati Sera, (ṣugbọn, Eri ati Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani) àwọn ọmọ ti Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Àwọn ọmọ ti Isakari ni: Tola, Pua, Jobu ati Ṣimironi. Àwọn ọmọ ti Sebuluni ni: Seredi, Eloni, ati Jaleeli. (Àwọn ni ọmọ tí Lea bí fún Jakọbu ní Padani-aramu ati Dina, ọmọ rẹ̀ obinrin.) Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin jẹ́ mẹtalelọgbọn. Àwọn ọmọ ti Gadi ni: Sifioni, Hagi, Ṣuni, Esiboni, Eri, Arodu, ati Areli. Àwọn ọmọ ti Aṣeri ni: Imina, Iṣifa, Iṣifi, Beraya, ati Sera arabinrin wọn. Àwọn ọmọ ti Beraya ni Heberi, ati Malikieli. (Àwọn ni ọmọ tí Silipa bí fún Jakọbu. Silipa ni iranṣẹ tí Labani fún Lea ọmọ rẹ̀ obinrin, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlogun.) Àwọn ọmọ ti Rakẹli ni Josẹfu ati Bẹnjamini. Asenati, ọmọbinrin Pọtifera bí Manase ati Efuraimu fún Josẹfu ní ilẹ̀ Ijipti. Pọtifera ni babalóòṣà oriṣa Oni, ní Ijipti. Àwọn ọmọ ti Bẹnjamini ni: Bela, Bekeri, Aṣibeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Hupimu, ati Aridi, (àwọn wọnyi ni ọmọ tí Rakẹli bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹrinla). Ọmọ ti Dani ni Huṣimu. Àwọn ọmọ ti Nafutali ni Jaseeli, Guni, Jeseri, ati Ṣilemu. (Àwọn ọmọ tí Biliha bí fún Jakọbu ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ meje), Biliha ni iranṣẹbinrin tí Labani fún Rakẹli, ọmọ rẹ̀ obinrin. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ijipti, tí wọ́n jẹ́ ọmọ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ jẹ́ mẹrindinlaadọrin, láìka àwọn iyawo àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ tí Josẹfu bí ní Ijipti jẹ́ meji. Gbogbo eniyan tí ó ti ìdílé Jakọbu jáde lọ sí Ijipti patapata wá jẹ́ aadọrin. Jakọbu rán Juda ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Josẹfu pé kí Josẹfu wá pàdé òun ní Goṣeni, wọ́n sì wá sí ilẹ̀ Goṣeni. Josẹfu bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó lọ pàdé Israẹli, baba rẹ̀ ní Goṣeni. Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́. Israẹli bá wí fún Josẹfu, ó ní, “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ojú kàn ọ́ báyìí, tí mo sì rí i pé o wà láàyè, bí ikú bá tilẹ̀ wá dé, ó yá mi.” Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo ìdílé baba rẹ̀ pé òun óo lọ sọ fún Farao pé àwọn arakunrin òun ati ìdílé baba òun tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Kenaani ti dé sọ́dọ̀ òun. Ati pé darandaran ni wọ́n, ìtọ́jú ẹran ọ̀sìn ni iṣẹ́ wọn, wọ́n sì kó gbogbo agbo mààlúù ati agbo ewúrẹ́, ati ohun gbogbo tí wọ́n ní lọ́wọ́ wá. Ó ní nígbà tí Farao bá pè wọ́n, tí ó bá bi wọ́n léèrè pé irú iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe, kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti.
Gẹn 46:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀. Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.” Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu. Àwọn ọmọkùnrin Reubeni: Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi. Àwọn ọmọkùnrin Simeoni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani. Àwọn ọmọkùnrin Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. Àwọn ọmọkùnrin: Isakari! Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni. Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni: Seredi, Eloni àti Jahaleli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀. Àwọn ọmọkùnrin Gadi: Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli. Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera. Àwọn ọmọkùnrin Beriah: Heberi àti Malkieli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀. Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu: Josẹfu àti Benjamini. Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu. Àwọn ọmọ Benjamini: Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀. Àwọn ọmọ Dani: Huṣimu. Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀. Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin. Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀. Jakọbu sì rán Juda ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Josẹfu, kí wọn bá à le mọ ọ̀nà Goṣeni. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Goṣeni, Josẹfu tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì lọ sí Goṣeni láti pàdé Israẹli baba rẹ̀. Bí Josẹfu ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́. Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara mi pé, o wà láààyè síbẹ̀.” Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá. Darandaran ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn àti agbo màlúù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú wá.’ Nígbà tí Farao bá pè yín wọlé tí ó sí béèrè irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe, ẹ fún un lésì pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn ni láti ìgbà èwe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.’ Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láààyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé àwọn ará Ejibiti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.”