Gẹn 45:3-13

Gẹn 45:3-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi ni Josefu; baba mi wà sibẹ̀? awọn arakunrin rẹ̀ kò si le da a lohùn; nitori ti ẹ̀ru bà wọn niwaju rẹ̀. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti. Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là. Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè. Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là. Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti. Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro. Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní. Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju. Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin. Ki ẹnyin ki o si ròhin gbogbo ogo mi ni Egipti fun baba mi, ati ti ohun gbogbo ti ẹnyin ri; ki ẹnyin ki o si yara, ki ẹ si mú baba mi sọkalẹ wá ihin.

Gẹn 45:3-13 Yoruba Bible (YCE)

Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bi wọ́n léèrè pé ǹjẹ́ baba òun ṣì wà láàyè. Ṣugbọn jìnnìjìnnì dà bo àwọn arakunrin rẹ̀ níwájú rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè dáhùn. Josẹfu bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ wọ́n, ó ní kí wọ́n jọ̀wọ́, kí wọ́n súnmọ́ òun. Ó tún wí fún wọn pé òun ni Josẹfu arakunrin wọn, tí wọ́n tà sí Ijipti. Ó ní, “Ẹ má wulẹ̀ dààmú ẹ̀mí ara yín, ẹ má sì bínú sí ara yín pé ẹ tà mí síhìn-ín. Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó rán mi ṣáájú yín láti gba ẹ̀mí là. Nítorí ó ti di ọdún keji tí ìyàn yìí ti bẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ yìí, ó sì ku ọdún marun-un gbáko tí kò fi ní sí ìfúrúgbìn tabi ìkórè. Ọlọrun ni ó rán mi ṣáájú yín láti dá yín sí, ati láti gba ọpọlọpọ ẹ̀mí là ninu ìran yín. Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé mi dé ìhín, Ọlọrun ni, ó sì ti fi mí ṣe baba fún Farao, ati oluwa ninu gbogbo ilé rẹ̀ ati alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ijipti. “Ẹ ṣe kíá, ẹ wá lọ sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ wí fún un pé, Josẹfu ọmọ rẹ̀ wí pé, Ọlọrun ti fi òun ṣe olórí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ẹ ní mo ní kí ó máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi kíákíá. Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní. N óo máa tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀, nítorí pé ó tún ku ọdún marun-un gbáko kí ìyàn yìí tó kásẹ̀ nílẹ̀, kí òun ati ìdílé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ má baà di aláìní. “Ẹ̀yin pàápàá fi ojú rí i, Bẹnjamini arakunrin mi náà sì rí i pẹlu pé èmi gan-an ni mò ń ba yín sọ̀rọ̀. Ẹ níláti sọ fún baba mi nípa gbogbo ògo mi ní Ijipti, ati gbogbo ohun tí ẹ ti rí. Ẹ tètè yára mú baba mi wá bá mi níhìn-ín.”

Gẹn 45:3-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti! Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín. Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀síwájú fún ọdún márùn-ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú-ọmọ yín sí fún un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là. “Nítorí náà kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ìhín bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba (Olùdámọ̀ràn) fún Farao, olúwa fún gbogbo ilé Farao àti alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nísinsin yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Josẹfu ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara. Ìwọ yóò gbé ní agbègbè Goṣeni, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní. Èmi yóò pèsè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó ṣì ku ọdún márùn-ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má ba à di aláìní. “Ẹ̀yin fúnrayín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀. Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.”