Gẹn 45:1-2
Gẹn 45:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Josefu kò le mu oju dá mọ́ niwaju gbogbo awọn ti o duro tì i; o si kigbe pe, Ẹ mu ki gbogbo enia ki o jade kuro lọdọ mi. Ẹnikẹni kò si duro tì i, nigbati Josefu sọ ara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀. O si sọkun kikan: ati awọn ara Egipti ati awọn ara ile Farao gbọ́.
Gẹn 45:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu. Ó bú sẹ́kún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pohùnréré ẹkún tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti ati gbogbo ilé Farao gbọ́ ẹkún rẹ̀.
Gẹn 45:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Josẹfu kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sọkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀.