Gẹn 43:15-34

Gẹn 43:15-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn ọkunrin na si mú ọrẹ na, nwọn si mú iṣẹ́po owo meji li ọwọ́ wọn, ati Benjamini; nwọn si dide, nwọn si sọkalẹ lọ si Egipti, nwọn si duro niwaju Josefu. Nigbati Josefu si ri Benjamini pẹlu wọn, o wi fun olori ile rẹ̀ pe, Mú awọn ọkunrin wọnyi rè ile, ki o si pa ẹran, ki o si pèse: nitori ti awọn ọkunrin wọnyi yio ba mi jẹun li ọjọkanri. Ọkunrin na si ṣe bi Josefu ti wi; ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na lọ si ile Josefu. Awọn ọkunrin na si mbẹ̀ru, nitori ti a mú wọn wá si ile Josefu; nwọn si wipe, Nitori owo ti a mú pada sinu àpo wa li akọ́wa li a ṣe mú wa wọle; ki o le fẹ wa lẹfẹ, ki o si le kọlù wa, ki o si le kó wa ṣe ẹrú ati awọn kẹtẹkẹtẹ wa. Nwọn si sunmọ iriju ile Josefu, nwọn si bá a sọ̀rọ li ẹnu-ọ̀na ile na, Nwọn si wipe, Alagba, nitõtọ li awa sọkalẹ wá ni iṣaju lati rà onjẹ: O si ṣe, nigbati awa dé ile-èro, ti awa tú àpo wa, si kiyesi i, owo olukuluku wà li ẹnu àpo rẹ̀, owo wa ni pípe ṣánṣan: awa si tun mú u li ọwọ́ pada wá. Owo miran li awa si mú li ọwọ́ wa sọkalẹ wá lati rà onjẹ: awa kò mọ̀ ẹniti o fi owo wa sinu àpo wa. O si wi fun wọn pe, Alafia ni fun nyin, ẹ má bẹ̀ru: Ọlọrun nyin ati Ọlọrun baba nyin, li o fun nyin ni iṣura ninu àpo nyin: owo nyin dé ọwọ́ mi. O si mú Simeoni jade tọ̀ wọn wá. Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ. Nwọn si ti mú ọrẹ na silẹ dè atibọ̀ Josefu lọsán: nitori ti nwọn gbọ́ pe nwọn o jẹun nibẹ̀. Nigbati Josefu si wọlé, nwọn si mú ọrẹ ti o wà li ọwọ́ wọn fun u wá sinu ile, nwọn si tẹriba fun u ni ilẹ. On si bère alafia wọn, o si wipe, Alafia ki baba nyin wà, arugbo na ti ẹnyin wi? o wà lãye sibẹ̀? Nwọn si dahun pe, Ara baba wa, iranṣẹ rẹ le, o wà sibẹ̀. Nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si bù ọlá fun u. O si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri Benjamini, aburo rẹ̀, ọmọ iya rẹ̀, o si wipe, Abikẹhin nyin na ti ẹnyin wi fun mi li eyi? o si wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe ojurere si ọ, ọmọ mi. Josefu si yara; nitori ti inu yọ́ ọ si aburo rẹ̀: o wá ibi ti yio gbé sọkun; o si bọ́ si iyẹwu, o si sọkun nibẹ̀. O si bọju rẹ̀, o si jade; o si mú oju dá, o si wipe, Ẹ gbé onjẹ kalẹ. Nwọn si gbé tirẹ̀ kalẹ fun u lọ̀tọ, ati fun wọn lọ̀tọ, ati fun awọn ara Egipti ti o mbá a jẹun lọ̀tọ; nitori ti awọn ara Egipti kò gbọdọ bá awọn enia Heberu jẹun; nitori irira ni fun awọn ara Egipti. Nwọn si joko niwaju rẹ̀, akọ́bi gẹgẹ bi ipò ibí rẹ̀, ati abikẹhin gẹgẹ bi ipò ewe rẹ̀: ẹnu si yà awọn ọkunrin na si ara wọn. O si bù onjẹ fun wọn lati iwaju rẹ̀ lọ: ṣugbọn onjẹ Benjamini jù ti ẹnikẹni wọn lẹrinmarun. Nwọn si mu, nwọn si bá a ṣe ariya.

Gẹn 43:15-34 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọkunrin náà bá gbé ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mú ìlọ́po meji owó tí wọ́n nílò, ati Bẹnjamini, wọ́n lọ siwaju Josẹfu ní Ijipti. Nígbà tí Josẹfu rí Bẹnjamini pẹlu wọn, ó sọ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Mú àwọn ọkunrin wọnyi wọlé, pa ẹran kan kí o sì sè é, nítorí wọn yóo bá mi jẹun lọ́sàn-án yìí.” Ọkunrin náà ṣe bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un, ó sì mú àwọn ọkunrin náà wọ ilé Josẹfu lọ. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” Wọ́n bá tọ alabojuto ilé Josẹfu lọ lẹ́nu ọ̀nà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, a ti kọ́kọ́ wá ra oúnjẹ níhìn-ín nígbà kan. Nígbà tí à ń pada lọ tí a dé ibi tí a fẹ́ sùn, a tú àpò wa, olukuluku wa bá owó tirẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀, kò sí ti ẹni tí ó dín rárá, a mú owó náà lọ́wọ́ báyìí. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ pẹlu láti ra oúnjẹ. A kò mọ ẹni tí ó dá owó wa pada sinu àpò wa.” Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ fọkàn yín balẹ̀, ẹ má bẹ̀rù, ó níláti jẹ́ pé Ọlọrun yín ati ti baba yín ni ó fi owó náà sinu àpò yín fun yín, mo gba owó lọ́wọ́ yín.” Ó bá mú Simeoni jáde sí wọn. Ọkunrin náà mú wọn wọ inú ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi, wọ́n fọ ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní oúnjẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n tọ́jú ẹ̀bùn Josẹfu sílẹ̀ di ìgbà tí yóo dé lọ́sàn-án, nítorí wọ́n gbọ́ pé ibẹ̀ ni wọn yóo ti jẹun. Nígbà tí Josẹfu wọlé, wọ́n mú ẹ̀bùn tí wọ́n mú bọ̀ fún un wọlé tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n sì wólẹ̀ fún un, wọ́n dojúbolẹ̀. Ó bèèrè alaafia wọn, ó ní, “Ṣé alaafia ni baba yín wà, arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi? Ṣé ó ṣì wà láàyè?” Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Baba wa, iranṣẹ rẹ ń bẹ láàyè, ó sì wà ní alaafia.” Wọ́n tẹríba, wọ́n bu ọlá fún un. Ojú tí ó gbé sókè, ó rí Bẹnjamini ọmọ ìyá rẹ̀, ó bá bèèrè pé, “Ṣé arakunrin yín tí í ṣe àbíkẹ́yìn tí ẹ wí nìyí? Kí Ọlọrun fi ojurere wò ọ́, ọmọ mi.” Josẹfu bá yára jáde kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí pé ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú, ó wá ibìkan láti lọ sọkún. Ó bá wọ yàrá rẹ̀, ó lọ sọkún níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ó bọ́ ojú rẹ̀, ó jáde, ó gbìyànjú, ó dárayá, ó ní, “Ẹ gbé oúnjẹ wá.” Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́tọ̀, ti àwọn arakunrin rẹ̀ lọ́tọ̀, ati ti àwọn ará Ijipti tí wọn ń bá a jẹun lọ́tọ̀, nítorí pé ìríra ni ó jẹ́ fún àwọn ará Ijipti láti bá àwọn Heberu jẹun pọ̀. Àwọn arakunrin Josẹfu jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n tò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, láti orí ẹ̀gbọ́n patapata dé orí àbúrò patapata. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i bí wọ́n ti tò wọ́n, wọ́n ń wo ara wọn lójú tìyanu-tìyanu. Láti orí tabili Josẹfu ni wọ́n ti bu oúnjẹ fún olukuluku, ṣugbọn oúnjẹ ti Bẹnjamini tó ìlọ́po marun-un ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá a jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì bá a ṣe àríyá.

Gẹn 43:15-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Benjamini, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Josẹfu. Nígbà tí Josẹfu rí Benjamini pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì ṣe àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.” Ọkùnrin náà sì ṣe bí Josẹfu ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu. Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Josẹfu, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ilé náà. Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá, ní òtítọ́ ni àwa ti sọ̀kalẹ̀ síhìn-ín láti wá ra oúnjẹ ní ìṣáájú. Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu un padà wá pẹ̀lú wa. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.” Ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà ni fún yín, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìṣúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Simeoni jáde tọ̀ wọ́n wá. Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú. Wọ́n pèsè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Josẹfu di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán. Nígbà tí Josẹfu dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó béèrè àlàáfíà wọn, ó sì wí pé, “Ṣé àlàáfíà ni baba yín wà, baba arúgbó tí ẹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣé ó sì wà láààyè?” Wọ́n dáhùn pé, “ìránṣẹ́ rẹ, baba wa sì wà láààyè, àlàáfíà sì ni ó wà pẹ̀lú.” Wọn sì tẹríba láti bọ̀wọ̀ fún un. Bí ó ti wò yíká tí ó sì rí Benjamini àbúrò rẹ̀, tí í ṣe ọmọ ìyá rẹ̀ gan an. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣe àbúrò yín tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn tí ẹ sọ fún mi nípa rẹ̀ nìyìí?” Ó sì tún wí pe, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún ọ, ọmọ mi” Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Josẹfu yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sọkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sọkún níbẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti bọ́jú tan, ó jáde wá, ó ṣe ọkàn ọkùnrin, ó sì wí fún wọn pé, kí wọ́n gbé oúnjẹ wá kí wọ́n le è jẹun. Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fún un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Ejibiti tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Ejibiti kò le bá ará Heberu jẹun nítorí ìríra pátápátá ló jẹ́ fún àwọn Ejibiti. A mú àwọn ọkùnrin náà jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bí wọ́n ṣe dàgbà sí, láti orí ẹ̀gbọ́n pátápátá dé orí èyí tí ó kéré pátápátá, wọ́n sì ń wo ara wọn tìyanu tìyanu. A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Josẹfu. Oúnjẹ Benjamini sì tó ìlọ́po márùn-ún ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láìsí ìdíwọ́.