Gẹn 42:1-6
Gẹn 42:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI Jakobu si ri pe ọkà wà ni Egipti, Jakobu wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eṣe ti ẹnyin fi nwò ara nyin li oju? O si wipe, Wò o, mo gbọ́ pe ọkà mbẹ ni Egipti: ẹ sọkalẹ lọ sibẹ̀, ki ẹ si rà fun wa lati ibẹ̀ wá; ki awa ki o le yè, ki a máṣe kú. Awọn arakunrin Josefu mẹwẹwa si sọkalẹ lọ lati rà ọkà ni Egipti. Ṣugbọn Jakobu kò rán Benjamini arakunrin Josefu pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; nitori ti o wipe, Ki ibi ki o má ba bá a. Awọn ọmọ Israeli si wá irà ọkà ninu awọn ti o wá: nitori ìyan na mú ni ilẹ Kenaani. Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ.
Gẹn 42:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún? Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.” Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà. Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà. Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani. Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
Gẹn 42:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.” Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú. Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu.