Gẹn 42:1-17

Gẹn 42:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI Jakobu si ri pe ọkà wà ni Egipti, Jakobu wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eṣe ti ẹnyin fi nwò ara nyin li oju? O si wipe, Wò o, mo gbọ́ pe ọkà mbẹ ni Egipti: ẹ sọkalẹ lọ sibẹ̀, ki ẹ si rà fun wa lati ibẹ̀ wá; ki awa ki o le yè, ki a máṣe kú. Awọn arakunrin Josefu mẹwẹwa si sọkalẹ lọ lati rà ọkà ni Egipti. Ṣugbọn Jakobu kò rán Benjamini arakunrin Josefu pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; nitori ti o wipe, Ki ibi ki o má ba bá a. Awọn ọmọ Israeli si wá irà ọkà ninu awọn ti o wá: nitori ìyan na mú ni ilẹ Kenaani. Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ. Josefu si ri awọn arakunrin rẹ̀, o si mọ̀ wọn, ṣugbọn o fi ara rẹ̀ ṣe àjeji fun wọn, o si sọ̀rọ akọ si wọn: o si wi fun wọn pe, Nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, Lati ilẹ Kenaani lati rà onjẹ. Josefu si mọ̀ awọn arakunrin rẹ̀, ṣugbọn awọn kò mọ̀ ọ. Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá. Nwọn si wi fun u pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, ṣugbọn lati rà onjẹ li awọn iranṣẹ rẹ ṣe wá. Ọmọ ẹnikan na ni gbogbo wa iṣe; olõtọ enia li awa, awa iranṣẹ rẹ ki iṣe amí. O si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn lati ri ìhoho ilẹ li ẹ ṣe wá. Nwọn si wipe, Arakunrin mejila li awa iranṣẹ rẹ, ọmọ ẹnikan na ni ilẹ Kenaani: si wò o, eyi abikẹhin si wà lọdọ baba wa loni-oloni, ọkan kò si sí. Josefu si wi fun wọn pe, On na li eyiti mo wi fun nyin pe, Amí li ẹnyin: Eyi bayi li a o fi ridi nyin, nipa ẹmi Farao bi ẹnyin o ti lọ nihin, bikoṣepe arakunrin abikẹhin nyin wá ihinyi. Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe. O si kó gbogbo wọn pọ̀ sinu túbu ni ijọ́ mẹta.

Gẹn 42:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.” Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú. Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu. Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Josẹfu mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n. Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ayọ́lẹ̀wò (Amí) ni yín, ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.” Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni, Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.” Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.” Josẹfu wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín! Èyí sì ni a ó fi dán an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Farao bá wà láààyè, ẹ kì yóò kúrò níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá sí ibí. Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta.

Gẹn 42:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún? Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.” Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà. Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà. Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani. Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n. Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà. Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.” Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.” Ṣugbọn Josẹfu tẹnumọ́ ọn pé, “Bí mo ti wí gan-an ni ọ̀rọ̀ rí, amí ni yín. Ohun tí n óo fi mọ̀ pé olóòótọ́ ni yín nìyí: mo fi orúkọ Farao búra, ẹ kò ní jáde níhìn-ín àfi bí ẹ bá mú àbíkẹ́yìn baba yín wá. Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.” Ó bá da gbogbo wọn sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹta.