Gẹn 41:41-57

Gẹn 41:41-57 Bibeli Mimọ (YBCV)

Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn; O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti. Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti. Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já. Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ. O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀. Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye. A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi. Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi. Ọdún meje ọ̀pọ na ti o wà ni ilẹ Egipti si pari. Ọdún meje ìyan si bẹ̀rẹ si dé, gẹgẹ bi Josefu ti wi: ìyan na si mú ni ilẹ gbogbo; ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Egipti li onjẹ gbé wà. Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe. Ìyan na si wà lori ilẹ gbogbo: Josefu si ṣí gbogbo ile iṣura silẹ, o si ntà fun awọn ara Egipti; ìyan na si nmú si i ni ilẹ Egipti. Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.

Gẹn 41:41-57 Yoruba Bible (YCE)

Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti. Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti. Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ. Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n. Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀. Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.” Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.” Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin. Ọdún meje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti wí, ìyàn mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣugbọn oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.” Nígbà tí ìyàn náà tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, Josẹfu ṣí àwọn àká tí wọ́n kó oúnjẹ pamọ́ sí, ó ń ta oúnjẹ fún àwọn ará Ijipti, nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé.

Gẹn 41:41-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Farao wí fún Josẹfu pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn. Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Èmi ni Farao. Ṣùgbọ́n láìsí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun ní ilẹ̀ Ejibiti.” Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí: Safenati-Panea èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Josẹfu nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Farao ọba Ejibiti. Josẹfu sì jáde kúrò níwájú Farao, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ejibiti Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà so èso lọ́pọ̀lọpọ̀. Josẹfu kó gbogbo oúnjẹ tí a pèsè ni ilẹ̀ Ejibiti ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí. Josẹfu pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí iyanrìn Òkun; ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà. Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Asenati ọmọ Potifẹra alábojútó Oni bí ọmọkùnrin méjì fún Josẹfu. Josẹfu sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Manase, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.” Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Efraimu, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi.” Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Ejibiti, Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Josẹfu ti wí gan an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tókù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Farao. Nígbà náà ni Farao wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Josẹfu, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.” Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Josẹfu ṣí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan an ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń wá sí Ejibiti láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Josẹfu, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.