Gẹn 41:15-16
Gẹn 41:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀. Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao.
Pín
Kà Gẹn 41Gẹn 41:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.”
Pín
Kà Gẹn 41Gẹn 41:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”
Pín
Kà Gẹn 41