Gẹn 4:6-7
Gẹn 4:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si bi Kaini pe, Ẽṣe ti inu fi mbi ọ? ẽ si ti ṣe ti oju rẹ̀ fi rẹ̀wẹsi? Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ? bi iwọ kò ba si ṣe rere, ẹ̀ṣẹ ba li ẹnu-ọ̀na, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yio ma fà si, iwọ o si ma ṣe alakoso rẹ̀.
Pín
Kà Gẹn 4Gẹn 4:6-7 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro? Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”
Pín
Kà Gẹn 4Gẹn 4:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA bi Kaini pé, “Èéṣe tí ìwọ ń bínú? Èéṣe tí ojú rẹ sì fàro? Bí ìwọ bá ṣe ohun tí ó tọ́, ṣé ìwọ kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ṣe ohun tí ó tọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ ní ọ ní ìní, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ ṣe àkóso rẹ̀.”
Pín
Kà Gẹn 4