Gẹn 4:25-26
Gẹn 4:25-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Adamu si tun mọ̀ aya rẹ̀, o si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: o wipe, nitori Ọlọrun yàn irú-ọmọ miran fun mi ni ipò Abeli ti Kaini pa. Ati Seti, on pẹlu li a bí ọmọkunrin kan fun; o si pè orukọ rẹ̀ ni Enoṣi: nigbana li awọn enia bẹ̀rẹ si ikepè orukọ OLUWA.
Gẹn 4:25-26 Yoruba Bible (YCE)
Adamu tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Seti, ó ní: “Ọlọrun tún fún mi ní ọmọ mìíràn dípò Abeli tí Kaini pa.” Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA.
Gẹn 4:25-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Adamu sì tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Seti, tí ó túmọ̀ sí pé, “Ọlọ́run fún mi ní ọmọkùnrin mìíràn ní ipò Abeli tí Kaini pa.” Seti náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Enoṣi. Láti àkókò náà lọ ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ké pe orúkọ OLúWA.