Gẹn 4:23-24
Gẹn 4:23-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lameki si wi fun awọn aya rẹ̀ pe, Ada on Silla, ẹ gbọ́ ohùn mi; ẹnyin aya Lameki, ẹ fetisi ọ̀rọ mi: nitoriti mo pa ọkunrin kan si ẹ̀dun mi, ati ọdọmọkunrin kan si ipalara mi. Bi a o gbẹsan Kaini lẹrinmeje, njẹ ti Lameki ni ìgba ãdọrin meje.
Gẹn 4:23-24 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá Lamẹki pe àwọn aya rẹ̀, ó ní: “Ada ati Sila, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin aya mi, ẹ gbọ́ mi ní àgbọ́yé: Mo pa ọkunrin kan nítorí pé ó pa mí lára, mo gba ẹ̀mí eniyan nítorí pé ó ṣá mi lọ́gbẹ́. Bí ẹ̀san ti Kaini bá jẹ́ ẹ̀mí eniyan meje, ẹ̀san ti Lamẹki gbọdọ̀ jẹ́ aadọrin ẹ̀mí ó lé meje.”
Gẹn 4:23-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lameki wí fún àwọn aya rẹ̀, “Adah àti Silla, ẹ tẹ́tí sí mi; ẹ̀yin aya Lameki, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Mo ti pa ọkùnrin kan tí ó kọlù mí, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó pa mí lára. Bí a ó bá gbẹ̀san Kaini ní ìgbà méje, ǹjẹ́ kí a gba ti Lameki nígbà mẹ́tà-dínlọ́gọ́rin.”