Gẹn 4:10-16
Gẹn 4:10-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, Kini iwọ ṣe nì? Ohùn ẹ̀jẹ arakunrin rẹ nkigbe pè mi lati inu ilẹ wá. Njẹ nisisiyi a fi ọ ré lori ilẹ, ti o yanu rẹ̀ gbà ẹ̀jẹ arakunrin rẹ lọwọ rẹ. Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye. Kaini si wi fun OLUWA pe, ìya ẹ̀ṣẹ mi pọ̀ jù eyiti emi lè rù lọ. Kiye si i, iwọ lé mi jade loni kuro lori ilẹ; emi o si di ẹniti o pamọ kuro loju rẹ; emi o si ma jẹ isansa ati alarinkiri li aiye; yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ri mi yio lù mi pa. OLUWA si wi fun u pe, Nitorina ẹnikẹni ti o ba pa Kaini a o gbẹsan lara rẹ̀ lẹrinmeje. OLUWA si sàmi si Kaini lara, nitori ẹniti o ba ri i ki o má ba pa a. Kaini si jade lọ kuro niwaju OLUWA, o si joko ni ilẹ Nodi, ni ìha ìla-õrùn Edeni.
Gẹn 4:10-16 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí. Wò ó! mo fi ọ́ gégùn-ún lórí ilẹ̀ tí ó mu ẹ̀jẹ̀ arakunrin rẹ tí o pa. Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Kaini dá OLUWA lóhùn, ó ní, “Ìjìyà yìí ti pọ̀jù fún mi. O lé mi kúrò lórí ilẹ̀, ati kúrò níwájú rẹ, n óo sì di ìsáǹsá ati alárìnká lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí ó bá yá, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi ni yóo pa mí.” Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á. Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu. Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni.
Gẹn 4:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA wí pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ṣe yìí? Gbọ́! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti ilẹ̀ wá. Láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ ti wà lábẹ́ ègún, a sì ti lé ọ lórí ilẹ̀ tí ó ya ẹnu gba ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ lọ́wọ́ rẹ. Bí ìwọ bá ro ilẹ̀, ilẹ̀ kì yóò fi agbára rẹ̀ so èso rẹ̀ fún ọ mọ́. Ìwọ yóò sì jẹ́ ìsáǹsá àti alárìnkiri ni orí ilẹ̀ ayé.” Kaini wí fún OLúWA pé, “Ẹrù ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi pọ̀ ju èyí tí mo le rù lọ. Lónìí, ìwọ lé mi kúrò lórí ilẹ̀, mó sì di ẹni tí ó fi ara pamọ́ kúrò ní ojú rẹ, èmi yóò sì di ìsáǹsá àti alárìnkiri ní ayé, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi, yóò sì pa mí.” Ṣùgbọ́n, OLúWA wí fún pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ẹnikẹ́ni bá pa Kaini, èmi yóò gbẹ̀san ní ara onítọ̀hún ní ìgbà méje.” Nígbà náà ni Ọlọ́run fi ààmì sí ara Kaini, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ri má ba à pa á. Kaini sì kúrò níwájú Ọlọ́run, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nodi ní ìhà ìlà-oòrùn Edeni.