Gẹn 39:1-6
Gẹn 39:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀. OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na. Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀. Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ. O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko. O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia.
Gẹn 39:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere. Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé. Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀. Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu. Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ. Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà.
Gẹn 39:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potiferi, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀. OLúWA sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé OLúWA wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé OLúWA jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé. Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún OLúWA wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko. Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀