Gẹn 38:19-23
Gẹn 38:19-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si dide, o ba tirẹ̀ lọ, o si bọ́ iboju rẹ̀ lelẹ kuro lara rẹ̀, o si mú aṣọ opó rẹ̀ ró. Judah si rán ọmọ ewurẹ na lati ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu na lọ, lati gbà ògo nì wá lọwọ obinrin na: ṣugbọn on kò ri i. Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin. O si pada tọ̀ Judah lọ, o si wipe, Emi kò ri i; ati pẹlu awọn ọkunrin ara ibẹ̀ na wipe, Kò sí panṣaga kan nibẹ̀. Judah si wipe, Jẹ ki o ma mú u fun ara rẹ̀, ki oju ki o má tì wa: kiyesi i, emi rán ọmọ ewurẹ yi, iwọ kò si ri i.
Gẹn 38:19-23 Yoruba Bible (YCE)
Ó dìde, ó bá tirẹ̀ lọ, ó ṣí ìbòjú rẹ̀ kúrò, ó sì tún wọ aṣọ ọ̀fọ̀ rẹ̀. Juda fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adulamu, sí Tamari, kí ó le bá a gba àwọn ohun tí ó fi dógò lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò bá a níbẹ̀ mọ́. Ó bi àwọn ọkunrin kan, ará ìlú náà pé, “Níbo ni obinrin aṣẹ́wó tí ó máa ń jókòó ní gbangba lẹ́bàá ọ̀nà Enaimu yìí wà?” Wọ́n dáhùn pé, “Kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan ní àdúgbò yìí.” Ọ̀rẹ́ Juda bá pada tọ̀ ọ́ lọ, ó ní òun kò rí i, ati pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀ sọ pé kò fi ìgbà kan sí aṣẹ́wó kankan níbẹ̀. Juda dá a lóhùn, ó ní, “Má wulẹ̀ wá a kiri mọ́, kí àwọn eniyan má baà máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Jẹ́ kí ó ṣe àwọn nǹkan ọwọ́ rẹ̀ bí ó bá ti fẹ́, mo ṣá fi àwọ́nsìn ewúrẹ́ tí mo ṣèlérí ranṣẹ, o kò rí i ni.”
Gẹn 38:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà. Juda sì rán ọmọ ewúrẹ́ náà láti ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adullamu náà lọ láti gba ògo n nì wá lọ́wọ́ obìnrin náà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀. Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni alágbèrè ojúbọ òrìṣà tí ó wà ní etí ọ̀nà Enaimu wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbí.” Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Juda ó wí fún un pé, “Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbẹ̀.” Nígbà náà ni Juda wí pé, “Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà. Mo sá à fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun.”