Gẹn 37:12-36
Gẹn 37:12-36 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan àwọn arakunrin rẹ̀ ń da agbo aguntan baba wọn lẹ́bàá Ṣekemu, Israẹli bá pe Josẹfu, ó ní, “Ǹjẹ́ Ṣekemu kọ́ ni àwọn arakunrin rẹ da ẹran lọ? Wò ó, wá kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu bá dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Israẹli sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, lọ bá mi wo alaafia àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ati ti àwọn agbo ẹran wá, kí o sì tètè pada wá jíṣẹ́ fún mi.” Israẹli bá rán an láti àfonífojì Heburoni lọ sí Ṣekemu. Níbi tí ó ti ń rìn kiri ninu pápá ni ọkunrin kan bá rí i, ó bi í pé, “Kí ni ò ń wá?” Josẹfu dáhùn pé, “Àwọn arakunrin mi ni mò ń wá, jọ̀wọ́, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n da agbo ẹran wọn lọ?” Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Wọ́n ti kúrò níhìn-ín, mo gbọ́ tí wọn ń bá ara wọn sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu bá tún lépa wọn lọ sí Dotani, ó sì bá wọn níbẹ̀. Bí wọ́n ti rí i tí ó yọ lókèèrè, kí ó tilẹ̀ tó súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn láti pa á. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, alálàá ni ó ń bọ̀ yìí! Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí á wọ́ ọ sinu kòtò kan, kí á sọ pé ẹranko burúkú kan ni ó pa á jẹ, kí á wá wò ó bí àlá rẹ̀ yóo ṣe ṣẹ.” Ṣugbọn nígbà tí Reubẹni gbọ́, ó gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó ní, “Ẹ má jẹ́ kí á pa á. Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, jíjù ni kí ẹ jù ú sinu kànga gbígbẹ láàrin aginjù yìí, ẹ má pa á lára rárá.” Ó fẹ́ fi ọgbọ́n yọ ọ́ lọ́wọ́ wọn, kí ó lè fi í ranṣẹ sí baba wọn pada. Bí Josẹfu ti dé ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, wọ́n fi ipá bọ́ ẹ̀wù aláràbarà rẹ̀ lọ́rùn rẹ̀, wọ́n gbé e jù sinu kànga kan tí kò ní omi ninu. Bí wọ́n ti jókòó tí wọ́n fẹ́ máa jẹun, ojú tí wọ́n gbé sókè, wọ́n rí ọ̀wọ́ àwọn ará Iṣimaeli kan, wọ́n ń bọ̀ láti Gileadi, wọ́n ń lọ sí Ijipti, àwọn ràkúnmí wọn ru turari, ìkunra olóòórùn dídùn ati òjíá. Juda bá sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Anfaani wo ni yóo jẹ́ fún wa bí a bá pa arakunrin wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣimaeli yìí. Ẹ má jẹ́ kí á pa á, nítorí arakunrin wa ni, ara kan náà ni wá.” Ọ̀rọ̀ náà sì dùn mọ́ àwọn arakunrin rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn oníṣòwò ará Midiani ń rékọjá lọ, wọ́n bá fa Josẹfu jáde láti inú kànga gbígbẹ náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣimaeli ní ogún owó fadaka. Àwọn ará Iṣimaeli sì mú Josẹfu lọ sí Ijipti. Nígbà tí Reubẹni pada dé ibi kànga gbígbẹ tí wọ́n ju Josẹfu sí, tí ó rí i pé kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Ó pada lọ bá àwọn arakunrin rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ọmọ náà kò sí níbẹ̀? Mo gbé! Ibo ni n óo yà sí?” Wọ́n bá mú ọmọ ewúrẹ́ kan ninu agbo, wọ́n pa á, wọ́n sì ti ẹ̀wù Josẹfu bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Wọ́n bá fi ẹ̀wù aláràbarà náà ranṣẹ sí baba wọn, wọ́n ní, “Ohun tí a rí nìyí. Wò ó wò, bóyá ẹ̀wù ọmọ rẹ ni, tabi òun kọ́.” Jakọbu yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì wí pé, “Ẹ̀wù ọmọ mi ni, ẹranko burúkú kan ti pa á, dájúdájú, ẹranko náà ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” Jakọbu bá fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọpọlọpọ ọjọ́. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin lọ láti tù ú ninu, ṣugbọn ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, ó ní, “Ninu ọ̀fọ̀ ni n óo wọ inú ibojì lọ bá ọmọ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni baba rẹ̀ sọkún rẹ̀. Àwọn ará Midiani tí wọ́n ra Josẹfu tà á fún Pọtifari, ará Ijipti, ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao. Pọtifari yìí ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba.
Gẹn 37:12-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣekemu. Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti Àfonífojì Hebroni. Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu, Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?” Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?” Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani. Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.” Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀, Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú rẹ̀. Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti. Juda wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kí ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi? Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ. Nítorí náà, nígbà tí àwọn oníṣòwò ara Midiani ń kọjá, àwọn arákùnrin Josẹfu fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣmaeli ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Josẹfu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí Reubeni padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Josẹfu kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́. Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdékùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?” Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Josẹfu, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà padà sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.” Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” Nígbà náà ni Jakọbu fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, lóbìnrin wá láti tù ú nínú, ṣùgbọ́n kò gbà. Ó wí pé, “Rárá, nínú ọ̀fọ̀ yìí ni èmi yóò lọ sí isà òkú lọ́dọ̀ ọmọ mi.” Baba Josẹfu sì sọkún fún un. Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, àwọn ará Midiani ta Josẹfu ní Ejibiti fún Potiferi, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao, tí í ṣe olórí ẹ̀ṣọ́.
Gẹn 37:12-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ lati bọ́ agbo-ẹran baba wọn ni Ṣekemu. Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi. O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu. Ọkunrin kan si ri i, si wò o, o nrìn kakiri ni pápa: ọkunrin na si bi i pe, Kini iwọ nwá? On si wipe, Emi nwá awọn arakunrin mi: mo bẹ̀ ọ, sọ ibi ti nwọn gbé mbọ́ agbo-ẹran wọn fun mi. Ọkunrin na si wipe, Nwọn ti lọ kuro nihin; nitori mo gbọ́, nwọn nwipe, ẹ jẹ ki a lọ si Dotani. Josefu si lepa awọn arakunrin rẹ̀, o si ri wọn ni Dotani. Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a. Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá. Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri. Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀. Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ. O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀; Nwọn si mú u, nwọn si gbe e sọ sinu ihò kan: ihò na si gbẹ, kò li omi. Nwọn si joko lati jẹun: nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn si wò, si kiyesi i, ọwọ́-èro ara Iṣmaeli nti Gileadi bọ̀; ti awọn ti ibakasiẹ ti o rù turari ati ikunra ati ojia, nwọn nmú wọn lọ si Egipti. Judah si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ere ki li o jẹ́ bi awa ba pa arakunrin wa, ti a si bò ẹ̀jẹ rẹ̀? Ẹ wá ẹ jẹ ki a tà a fun awọn ara Iṣmaeli ki a má si fọwọ wa kàn a; nitori arakunrin wa ati ara wa ni iṣe. Awọn arakunrin rẹ̀ si gbà tirẹ̀. Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti. Reubeni si pada lọ si ihò; si wò o, Josefu kò sí ninu ihò na; o si fà aṣọ rẹ̀ ya. O si pada tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wipe, Ọmọde na kò sí; ati emi, nibo li emi o gbé wọ̀? Nwọn si mú ẹ̀wu Josefu, nwọn si pa ọmọ ewurẹ kan, nwọn si rì ẹ̀wu na sinu ẹ̀jẹ na. Nwọn si fi ẹ̀wu alarabara aṣọ na ranṣẹ, nwọn si mú u tọ̀ baba wọn wá; nwọn si wipe, Eyi li awa ri: mọ̀ nisisiyi bi ẹ̀wu ọmọ rẹ ni, bi on kọ́. On si mọ̀ ọ, o si wipe, Ẹ̀wu ọmọ mi ni; ẹranko buburu ti pa a jẹ; li aiṣe aniani, a ti fà Josefu ya pẹrẹpẹrẹ. Jakobu si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si ṣọ̀fọ ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ pupọ̀. Ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ obinrin dide lati ṣìpẹ fun u; ṣugbọn o kọ̀ lati gbipẹ̀; o si wipe, Ninu ọ̀fọ li emi o sa sọkalẹ tọ̀ ọmọ mi lọ si isà-okú. Bayi ni baba rẹ̀ sọkun rẹ̀. Awọn ara Midiani si tà a si Egipti fun Potifari, ijoye Farao kan, ati olori ẹṣọ́.