Gẹn 35:11-12
Gẹn 35:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá; Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun.
Gẹn 35:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde. N óo fún ọ ní ilẹ̀ tí mo fún Abrahamu ati Isaaki, àwọn ọmọ rẹ ni yóo sì jogún rẹ̀.”
Gẹn 35:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai); máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.”