Gẹn 31:17-55

Gẹn 31:17-55 Yoruba Bible (YCE)

Jakọbu bá dìde, ó gbé àwọn ọmọ ati àwọn aya rẹ̀ gun ràkúnmí. Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani. Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó. Ọgbọ́n ni Jakọbu lò fún Labani ará Aramea, nítorí pé Jakọbu kò sọ fún un pé òun fẹ́ sálọ. Ó dìde, ó kó gbogbo ohun tí ó ní, ó sá gòkè odò Yufurate, ó doríkọ ọ̀nà agbègbè olókè Gileadi. Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n sọ fún Labani pé Jakọbu ti sálọ, ó kó àwọn ìbátan rẹ̀, ó sì tọpa rẹ̀ fún ọjọ́ meje, ó bá a ní agbègbè olókè Gileadi. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún Labani ará Aramea lóru lójú àlá, ó ní, “Ṣọ́ra, má bá Jakọbu sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.” Labani lé Jakọbu bá níbi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní orí òkè náà, Labani ati àwọn ìbátan rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí agbègbè olókè Gileadi. Labani pe Jakọbu, ó ní, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí? O tàn mí jẹ, o sì kó àwọn ọmọbinrin mi sá bí ẹrú tí wọ́n kó lójú ogun. Èéṣe tí o fi tàn mí jẹ, tí o yọ́ lọ láìsọ fún mi? Ṣebí ǹ bá fi ayọ̀, ati orin ati ìlù ati hapu sìn ọ́. Èéṣe tí o kò fún mi ní anfaani láti fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi lẹ́nu kí n fi dágbére fún wọn? Ìwà òmùgọ̀ ni o hù yìí. Mo ní agbára láti ṣe ọ́ níbi, ṣugbọn Ọlọrun baba rẹ bá mi sọ̀rọ̀ ní òru àná pé kí n ṣọ́ra, kí n má bá ọ sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu. Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?” Jakọbu bá dá Labani lóhùn, ó ní, “Ẹ̀rù ni ó bà mí, mo rò pé o óo fi ipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi. Ní ti àwọn ère oriṣa rẹ, bí o bá bá a lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Níwájú gbogbo ìbátan wa, tọ́ka sí ohunkohun tí ó bá jẹ́ tìrẹ ninu gbogbo ohun tí ó wà lọ́dọ̀ mi, kí o sì mú un.” Jakọbu kò mọ̀ rárá pé Rakẹli ni ó jí àwọn ère oriṣa Labani kó. Labani bá wá inú àgọ́ Jakọbu, ati ti Lea ati ti àwọn iranṣẹbinrin mejeeji, ṣugbọn kò rí àwọn ère oriṣa rẹ̀. Bí ó ti jáde ninu àgọ́ Lea ni ó lọ sí ti Rakẹli. Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn. Rakẹli wí fún baba rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, má bínú pé n kò dìde lójú kan tí mo jókòó sí, mò ń ṣe nǹkan oṣù mi lọ́wọ́ ni.” Bẹ́ẹ̀ ni Labani ṣe wá àwọn ère oriṣa rẹ̀ títí, ṣugbọn kò rí wọn. Inú wá bí Jakọbu, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Labani, ó ní, “Kí ni mo ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ tí o fi ń tọpa mi kíkankíkan bẹ́ẹ̀? Nígbà tí o tú gbogbo ẹrù mi palẹ̀, àwọn nǹkan rẹ wo ni o rí níbẹ̀? Kó o kalẹ̀ níwájú àwọn ìbátan mi ati àwọn ìbátan rẹ, kí wọ́n lè dájọ́ láàrin wa. Fún ogún ọdún tí mo fi bá ọ gbé, ewúrẹ́ rẹ kan tabi aguntan kan kò sọnù rí, bẹ́ẹ̀ ni n kò jí àgbò rẹ kan pajẹ rí. Èyí tí ẹranko burúkú bá pajẹ tí n kò bá gbé òkú rẹ̀ wá fún ọ, èmi ni mò ń fara mọ́ ọn. O máa ń gba ààrọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ mi, ìbáà jẹ́ ní òru ni ó sọnù tabi ní ọ̀sán. Bẹ́ẹ̀ ni mò ń wà ninu oòrùn lọ́sàn-án ati ninu òtútù lóru, oorun kò sì sí lójú mi. Ó di ogún ọdún tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, mo fi ọdún mẹrinla sìn ọ́ nítorí àwọn ọmọbinrin rẹ, ati ọdún mẹfa fún agbo ẹran rẹ. Ìgbà mẹ́wàá ni o sì pa owó ọ̀yà mi dà. Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi, àní, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun tí Isaaki ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, láìsí àní àní, ìwọ ìbá ti lé mi lọ lọ́wọ́ òfo kó tó di àkókò yìí. Ọlọrun rí ìyà mi ati iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó fi kìlọ̀ fún ọ ní alẹ́ àná.” Labani bá dá Jakọbu lóhùn, ó ní, “Èmi ni mo ni àwọn ọmọbinrin wọnyi, tèmi sì ni àwọn ọmọ wọnyi pẹlu, èmi náà ni mo ni àwọn agbo ẹran, àní gbogbo ohun tí ò ń wò wọnyi, èmi tí mo ni wọ́n nìyí. Ṣugbọn kí ni mo lè ṣe lónìí sí àwọn ọmọbinrin mi wọnyi ati sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí? Ó dára, jẹ́ kí èmi pẹlu rẹ dá majẹmu, kí majẹmu náà sì jẹ́ ẹ̀rí láàrin àwa mejeeji.” Jakọbu bá gbé òkúta kan, ó fi sọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n. Ó sì sọ fún àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n kó òkúta jọ. Wọ́n sì kó òkúta jọ, wọ́n fi ṣe òkítì ńlá kan, gbogbo wọn bá jọ jẹun níbi òkítì náà. Labani sọ ibẹ̀ ní Jegari Sahaduta, ṣugbọn Jakọbu pè é ní Galeedi. Labani wí pé, “Òkítì yìí ni ohun ẹ̀rí láàrin èmi pẹlu rẹ lónìí.” Nítorí náà ó sọ ọ́ ní Galeedi. Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa. Bí o bá fi ìyà jẹ àwọn ọmọbinrin mi, tabi o tún fẹ́ obinrin mìíràn kún àwọn ọmọbinrin mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan pẹlu wa, ranti o, Ọlọrun ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa mejeeji.” Labani bá sọ fún Jakọbu pé, “Wo òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí, tí mo ti gbé kalẹ̀ láàrin àwa mejeeji. Òkítì yìí ati ọ̀wọ̀n yìí sì ni ẹ̀rí pẹlu pé n kò ní kọjá òkítì yìí láti wá gbógun tì ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà kò ní kọjá òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí láti wá gbógun tì mí. Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. Jakọbu bá rúbọ lórí òkè náà, ó pe àwọn ìbátan rẹ̀ láti jẹun, wọ́n sì wà lórí òkè náà ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu láti dágbére fún wọn, ó súre fún wọn, ó sì pada sílé.

Gẹn 31:17-55 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Jakobu dide, o si gbé awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn aya rẹ̀ gùn ibakasiẹ. O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani. Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ. Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ. Bẹ̃li o kó ohun gbogbo ti o ní salọ: o si dide, o si kọja odò, o si kọju rẹ̀ si oke Gileadi. A si wi fun Labani ni ijọ́ kẹta pe, Jakobu salọ. O si mú awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si lepa rẹ̀ ni ìrin ijọ́ meje: o si bá a li oke Gileadi. Ọlọrun si tọ̀ Labani, ara Siria wá li oru li oju-alá, o si wi fun u pe, Kiyesi ara rẹ, ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu. Nigbana ni Labani bá Jakobu. Jakobu ti pa agọ́ rẹ̀ li oke na: ati Labani pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ dó li oke Gileadi. Labani si wi fun Jakobu pe, Kini iwọ ṣe nì, ti iwọ tàn mi jẹ ti iwọ si kó awọn ọmọbinrin mi lọ bi ìgbẹsin ti a fi idà mú? Ẽṣe ti iwọ fi salọ li aṣíri, ti iwọ si tàn mi jẹ; ti iwọ kò si wi fun mi ki emi ki o le fi ayọ̀ ati orin, ati ìlu, ati dùru, sìn ọ; Ti iwọ kò si jẹ ki emi fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin mi li ẹnu? iwọ ṣiwere li eyiti iwọ ṣe yi. O wà ni ipa mi lati ṣe nyin ni ibi: ṣugbọn Ọlọrun baba nyin ti sọ fun mi li oru aná pe, Kiyesi ara rẹ ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu. Ati nisisiyi, iwọ kò le ṣe ailọ, nitori ti ọkàn rẹ fà gidigidi si ile baba rẹ, ṣugbọn ẽhaṣe ti iwọ fi jí awọn oriṣa mi lọ? Jakobu si dahùn o si wi fun Labani pe, Nitori ti mo bẹ̀ru ni: nitori ti mo wipe, iwọ le fi agbara gbà awọn ọmọbinrin rẹ lọwọ mi. Lọwọ ẹnikẹni ti iwọ ba ri awọn oriṣa rẹ ki o máṣe wà lãye: li oju awọn arakunrin wa wọnyi, wá ohun ti iṣe tirẹ lọdọ mi, ki o si mú u si ọdọ rẹ. Jakobu kò sa mọ̀ pe Rakeli ti jí wọn. Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ. Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn. O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na. Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃? Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji. Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ. Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru. Bayi ni mo wà; ongbẹ ngbẹ mi li ọsán, otutù si nmu mi li oru: orun mi si dá kuro li oju mi. Bayi li o ri fun mi li ogún ọdún ni ile rẹ; mo sìn ọ li ọdún mẹrinla nitori awọn ọmọbinrin rẹ mejeji, ati li ọdún mẹfa nitori ohun-ọ̀sin rẹ: iwọ si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa. Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná. Labani si dahùn o si wi fun Jakobu pe, Awọn ọmọbinrin wọnyi, awọn ọmọbinrin mi ni, ati awọn ọmọ wọnyi, awọn ọmọ mi ni, ati awọn ọwọ́-ẹran wọnyi ọwọ́-ẹran mi ni, ati ohun gbogbo ti o ri ti emi ni: kili emi iba si ṣe si awọn ọmọbinrin mi wọnyi loni, tabi si awọn ọmọ wọn ti nwọn bí? Njẹ nisisiyi, wá, jẹ ki a bá ara wa dá majẹmu, temi tirẹ; ki o si ṣe ẹrí lãrin temi tirẹ. Jakobu si mú okuta kan, o si gbé e ró ṣe ọwọ̀n. Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na. Labani si sọ orukọ rẹ̀ ni Jegari-Sahaduta: ṣugbọn Jakobu sọ ọ ni Galeedi. Labani si wipe, Òkiti yi li ẹri lãrin temi tirẹ loni. Nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Galeedi: Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa. Bi iwọ ba pọ́n awọn ọmọbinrin mi li oju, tabi bi iwọ ba fẹ́ aya miran pẹlu awọn ọmọbinrin mi, kò sí ẹnikan pẹlu wa; wò o, Ọlọrun li ẹlẹri lãrin temi tirẹ. Labani si wi fun Jakobu pe, Wò òkiti yi, si wò ọwọ̀n yi, ti mo gbé ró lãrin temi tirẹ. Òkiti yi li ẹri, ọwọ̀n yi li ẹri, pe emi ki yio rekọja òkiti yi sọdọ rẹ; ati pe iwọ ki yio si rekọja òkiti yi ati ọwọ̀n yi sọdọ mi fun ibi. Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Nahori, Ọlọrun baba wọn, ni ki o ṣe idajọ lãrin wa. Jakobu si fi ẹ̀ru Isaaki baba rẹ̀ bura. Nigbana ni Jakobu rubọ lori oke na, o si pè awọn arakunrin rẹ̀ wá ijẹun: nwọn si jẹun, nwọn si fi gbogbo oru ijọ́ na sùn lori oke na. Ni kutukutu owurọ̀ Labani si dide, o si fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ li ẹnu, o si sure fun wọn: Labani si dide, o si pada lọ si ipò rẹ̀.

Gẹn 31:17-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Jakọbu gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ìbákasẹ. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kójọ ni Padani-Aramu, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí Labani sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rakeli sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀. Síwájú sí i, Jakọbu tan Labani ará Aramu, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sálọ. Ó sì sálọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Eufurate), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gileadi. Ní ọjọ́ kẹta ni Labani gbọ́ pé Jakọbu ti sálọ. Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jakọbu, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gileadi. Ọlọ́run sì yọ sí Labani ará Aramu lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.” Jakọbu ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Labani bá a. Labani àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tì wọ́n sí ilẹ̀ òkè Gileadi. Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú. Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ àti orin, pẹ̀lú ìlù àti ohun èlò orin sìn ọ́. Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí. Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú. Nísinsin yìí, ìwọ ti lọ nítorí ìwọ fẹ́ láti padà lọ sí ilé baba rẹ, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìwọ fi jí àwọn òrìṣà mi?” Jakọbu dá Labani lóhùn pé, “Ẹ̀rù ni ó bà mi nítorí, mo rò pé ìwọ le fi tipátipá gba àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ mi. Ṣùgbọ́n bí o bá ri ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ère rẹ, kí ẹni náà di òkú. Ó tún wí pé, Níwájú gbogbo ìbátan wa báyìí, wò ó fúnrarẹ̀, bí o bá rí ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ, mú un.” Jakọbu kò sì mọ̀ pé, Rakeli ni ó jí àwọn òrìṣà náà. Labani sì lọ sínú àgọ́ Jakọbu àti ti Lea àti ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Lea ni ó lọ sí àgọ́ Rakeli. Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun. Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà. Inú sì bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjà pé, “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn? Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kí ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrín àwa méjèèjì. “Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ. Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn. Báyìí ni ohun gbogbo rí fún ogún ọdún tí mo fi wà nínú ilé rẹ. Ọdún mẹ́rìnlá ni mo fi sìn ọ́ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì sìn ọ fún ọdún mẹ́fà fún àwọn ẹran ọ̀sìn, lẹ́ẹ̀mẹ́wàá ni o sì yí owó iṣẹ́ mi padà. Bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run àwọn baba mi, Ọlọ́run Abrahamu àti ẹ̀rù Isaaki kò wà pẹ̀lú mi ni, ìwọ ìbá ti lé mi jáde lọ́wọ́ òfo. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ti rí gbogbo ìpọ́njú mi àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ó sì kìlọ̀ fún ọ lóru àná.” Labani sì dá Jakọbu lóhùn, “Tèmi ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, ọmọ mi ni àwọn ọmọ wọ̀nyí pẹ̀lú, àwọn agbo ẹran yìí, tèmi ni wọ́n pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí o rí wọ̀nyí, tèmi ni. Kí ni mo wá le ṣe sí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àti àwọn ọmọ wọn tí wọn bí? Wá, jẹ́ kí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú ara wa, èyí yóò sì jẹ́ ẹ̀rí ní àárín wa.” Jakọbu sì mú òkúta kan ó sì gbé e dúró bí ọ̀wọ́n. Ó sì wí fún àwọn ìbátan rẹ̀ pé, “Ẹ kó àwọn òkúta díẹ̀ jọ.” Wọ́n sì kó òkúta náà jọ bí òkìtì wọ́n sì jẹun níbẹ̀. Labani sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jegari-Sahaduta, ṣùgbọ́n Jakọbu pè é ni Galeedi. Labani sì wí pé, “Òkìtì yìí jẹ́ ẹ̀rí láàrín èmi àti ìwọ ní òní.” Ìdí nìyí tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ni Galeedi. Ó tún pè é ni Mispa nítorí, ó wí pé, “Kí OLúWA kí ó máa ṣọ́ èmi àti ìwọ nígbà tí a bá yà kúrò lọ́dọ̀ ara wa tán. Bí o bá fìyà jẹ àwọn ọmọbìnrin mi, tàbí tí o fẹ́ aya mìíràn yàtọ̀ sí wọn, rántí pé, Ọlọ́run ń bẹ láàrín wa bí ẹlẹ́rìí bí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ sí.” Labani tún sọ síwájú fún Jakọbu pé, “Òkìtì àti ọ̀wọ̀n tí mo gbé kalẹ̀ láàrín èmi àti ìwọ yìí, yóò jẹ́ ẹ̀rí wí pé èmi kò ni ré ọ̀wọ̀n àti òkìtì yìí kọjá láti bá ọ jà àti pé ìwọ pẹ̀lú kì yóò kọjá òkìtì tàbí ọ̀wọ̀n yìí láti ṣe mí ní ibi. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Nahori, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrín wa.” Jakọbu sì fi ẹ̀rù Isaaki baba rẹ̀ búra. Jakọbu sì rú ẹbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Labani sì padà lọ sí ilé.