Gẹn 3:23-24
Gẹn 3:23-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá. Bẹ̃li o lé ọkunrin na jade; o si fi awọn kerubu ati idà ina dè ìha ìla-õrùn Edeni ti njù kakiri, lati ma ṣọ́ ọ̀na igi ìye na.
Gẹn 3:23-24 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde. Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.
Gẹn 3:23-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, OLúWA Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá. Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni.