Gẹn 3:17-19
Gẹn 3:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gbà ohùn aya rẹ gbọ́, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; Ẹgún on oṣuṣu ni yio ma hù jade fun ọ, iwọ o si ma jẹ eweko igbẹ: Li õgùn oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.
Gẹn 3:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Ó sọ fún Adamu, pé, “Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ, o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ, mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ. Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ, ewéko ni o óo sì máa jẹ. Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.”
Gẹn 3:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ. Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”