Gẹn 29:31-35
Gẹn 29:31-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan. Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni. O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.
Gẹn 29:31-35 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA rí i pé Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó fún Lea ní ọmọ bí, ṣugbọn Rakẹli yàgàn. Lea lóyún, ó bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Reubẹni, ó ní, “Nítorí OLUWA ti ṣíjú wo ìpọ́njú mi; nisinsinyii, ọkọ mi yóo fẹ́ràn mi.” Ó tún lóyún, ó tún bí ọkunrin, ó ní, “Nítorí pé OLUWA ti gbọ́ pé wọ́n kórìíra mi ni ó ṣe fún mi ní ọmọ yìí pẹlu.” Ó bá sọ ọ́ ní Simeoni. Ó tún lóyún, ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Ọkọ mi gbọdọ̀ faramọ́ mi wàyí, nítorí pé ó di ọkunrin mẹta tí mo bí fún un”, nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Lefi. Ó tún lóyún ó sì tún bí ọkunrin, ó ní, “Wàyí o, n óo yin OLUWA,” ó bá sọ ọ́ ní Juda. Lẹ́yìn rẹ̀, kò bímọ mọ́.
Gẹn 29:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Ọlọ́run sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n Rakeli yàgàn. Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Reubeni, nítorí ó wí pé, “Nítorí Ọlọ́run ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Simeoni, wí pé “Nítorí tí OLúWA ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.” Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Lefi. Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin OLúWA.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Juda. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.