Gẹn 28:12-15
Gẹn 28:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀. Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ. Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye. Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan.
Gẹn 28:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò. OLUWA pàápàá dúró lókè rẹ̀, ó wí fún un pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun Abrahamu baba rẹ ati Ọlọrun Isaaki, ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi fún. Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé. Wò ó, mo wà pẹlu rẹ, n óo pa ọ́ mọ́ níbikíbi tí o bá lọ, n óo sì mú ọ pada wá sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé n kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí tí n óo fi ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún ọ.”
Gẹn 28:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. OLúWA sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni OLúWA, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”