Gẹn 28:1-22
Gẹn 28:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé; “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani. Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ. Kí Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn. Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Abrahamu, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Abrahamu.” Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau. Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu. Nígbà náà ni Esau mọ bí Isaaki baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kenaani tó. Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀. Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. OLúWA sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni OLúWA, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.” Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú OLúWA ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.” Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí. Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà OLúWA ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”
Gẹn 28:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
ISAAKI si pè Jakobu, o si sùre fun u, o si kìlọ fun u, o si wi fun u pe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani. Dide, lọ si Padan-aramu, si ile Betueli, baba iya rẹ; ki iwọ ki o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ wá ninu awọn ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ. Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o si mu ọ bisi i, ki o si mu ọ rẹ̀ si i, ki iwọ ki o le di ọ̀pọlọpọ enia. Ki o si fi ibukún Abrahamu fun ọ, fun iwọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ; ki iwọ ki o le ni ilẹ na ninu eyiti iwọ nṣe atipo, ti Ọlọrun fi fun Abrahamu. Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau. Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu: Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀; Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni. Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani. O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na. O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀. Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ. Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye. Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan. Jakobu si jí li oju-orun rẹ̀, o si wipe, OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ̀. Ẹrù si bà a, o si wipe, Ihinyi ti li ẹ̀ru tó! eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun. Jakobu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si mu okuta ti o fi ṣe irọri rẹ̀, o si fi lelẹ fun ọwọ̀n, o si ta oróro si ori rẹ̀. O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri. Jakobu si jẹ́ ẹjẹ́ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ́ li ọ̀na yi ti emi ntọ̀, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora, Ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi. Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.
Gẹn 28:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Isaaki bá pe Jakọbu, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani. Ó ní, “Dìde, lọ sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, ní Padani-aramu, kí o sì fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Labani, arakunrin ìyá rẹ. Ọlọrun Olodumare yóo bukun ọ, yóo fún ọ ní ọmọ pupọ, yóo sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá. Ìre tí ó sú fún Abrahamu yóo mọ́ ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lórí. Ilẹ̀ tí ó fún Abrahamu, níbi tí Abrahamu ti jẹ́ àjèjì yóo sì di tìrẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki ṣe rán Jakọbu jáde lọ sí Padani-aramu lọ́dọ̀ Labani, ọmọ Betueli, ará Aramea, arakunrin Rebeka, ìyá Jakọbu ati Esau. Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani. Ó sì tún rí i pé Jakọbu gbọ́ ti baba ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Padani-aramu bí wọ́n ti sọ, ati pé inú Isaaki, baba wọn kò dùn sí i pé kí wọn fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kenaani níyàwó. Nítorí náà Esau lọ sọ́dọ̀ Iṣimaeli ọmọ Abrahamu, ó sì fẹ́ Mahalati ọmọ rẹ̀, tíí ṣe arabinrin Nebaiotu, ó fi kún àwọn aya tí ó ti ní. Jakọbu kúrò ní Beeriṣeba, ó ń lọ sí Harani. Nígbà tí ó dé ibìkan tí ó rí i pé ilẹ̀ ti ń ṣú, ó gbé ọ̀kan ninu àwọn òkúta tí ó wà níbẹ̀, ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò. OLUWA pàápàá dúró lókè rẹ̀, ó wí fún un pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun Abrahamu baba rẹ ati Ọlọrun Isaaki, ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi fún. Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé. Wò ó, mo wà pẹlu rẹ, n óo pa ọ́ mọ́ níbikíbi tí o bá lọ, n óo sì mú ọ pada wá sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé n kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí tí n óo fi ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún ọ.” Nígbà tí Jakọbu tají ní ojú oorun rẹ̀, ó ní, “Dájúdájú OLUWA ń bẹ níhìn-ín, n kò sì mọ̀!” Ẹ̀rù bà á, ó sì wí pé, “Ààrin yìí mà tilẹ̀ bani lẹ́rù pupọ o! Ibí yìí kò lè jẹ́ ibòmíràn bíkòṣe ilé Ọlọrun, ibí gan-an ni ẹnu ibodè ọ̀run.” Jakọbu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí nàró gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n, ó sì da òróró sórí rẹ̀. Ó sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli, ṣugbọn Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí. Jakọbu bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan, ó ní “Bí Ọlọrun bá wà pẹlu mi, bí ó bá sì pa mí mọ́ ní ọ̀nà ibi tí mò ń lọ yìí, tí ó bá fún mi ní oúnjẹ jẹ, tí ó sì fún mi ni aṣọ wọ̀, tí mo bá sì pada dé ilé baba mi ní alaafia, OLUWA ni yóo máa jẹ́ Ọlọrun mi. Òkúta tí mo sì gbé nàró bí ọ̀wọ̀n yìí yóo di ilé Ọlọrun, n óo sì fún ìwọ Ọlọrun ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí o bá fún mi.”