Gẹn 25:22-26
Gẹn 25:22-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ si njàgudu ninu rẹ̀: o si wipe, bi o ba ṣe pe bẹ̃ni yio ri, ẽṣe ti mo fi ri bayi? O si lọ bère lọdọ OLUWA. OLUWA si wi fun u pe, orilẹ-ède meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le jù ekeji lọ; ẹgbọ́n ni yio si ma sìn aburo. Nigbati ọjọ́ rẹ̀ ti yio bí si pé, si kiyesi i, ibeji li o wà ninu rẹ̀. Akọ́bi si jade wá, o pupa, ara rẹ̀ gbogbo ri bí aṣọ onirun; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Esau. Ati lẹhin eyini li arakunrin rẹ̀ jade wá, ọwọ́ rẹ̀ si dì gigĩsẹ Esau mu; a si sọ orukọ rẹ̀ ni Jakobu: Isaaki si jẹ ẹni ọgọta ọdún nigbati Rebeka bí wọn.

Gẹn 25:22-26 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ, a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà, ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ, èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.” Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́. Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau. Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn.
Gẹn 25:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ OLúWA. OLúWA sì wí fún un pé, “Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ, irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ; àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ, ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” Nígbà tí ó tó àkókò fún un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n. Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Esau. Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin èkejì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di Esau ni gìgísẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jakọbu. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Isaaki, nígbà tí Rebeka bí wọn.