Gẹn 24:52-67

Gẹn 24:52-67 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA. Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀. Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi. Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ. On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ. Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀. Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ. Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ. Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn. Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ. Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé. Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá. Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ. Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀. Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki. Isaaki si mu u wá si inu agọ́ Sara, iya rẹ̀, o si mu Rebeka, o di aya rẹ̀; o si fẹ́ ẹ; a si tu Isaaki ninu lẹhin ikú iya rẹ̀.

Gẹn 24:52-67 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA. Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu. Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.” Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!” Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” Wọ́n bá pe Rebeka, wọ́n bi í pé, “Ṣé o óo máa bá ọkunrin yìí lọ?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ.” Wọ́n bá gbà pé kí Rebeka arabinrin wọn máa lọ, pẹlu olùtọ́jú rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, pẹlu àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.” Rebeka ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ bá gun ràkúnmí, wọ́n tẹ̀lé ọkunrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni iranṣẹ náà ṣe mú Rebeka lọ. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Isaaki ti wá láti Beeri-lahai-roi, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nẹgẹbu. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀. Ojú tí Rebeka náà gbé sókè, ó rí Isaaki, ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkúnmí. Ó bi iranṣẹ Abrahamu náà pé, “Ta ni ó ń rìn ninu pápá lọ́ọ̀ọ́kán tí ó ń bọ̀ wá pàdé wa yìí?” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Olúwa mi ni.” Rebeka bá mú ìbòjú rẹ̀, ó dà á bojú. Nígbà tí wọ́n pàdé Isaaki, iranṣẹ náà ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. Isaaki bá mú Rebeka wọ inú àgọ́ Sara ìyá rẹ̀, Rebeka sì di aya rẹ̀, Isaaki sì fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà yìí ni Isaaki kò tó ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́.

Gẹn 24:52-67 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ọmọ ọ̀dọ̀ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú OLúWA. Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rebeka, ó fún arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.” Ṣùgbọ́n arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rebeka wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn èyí, ìwọ le máa mu lọ.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá mi dúró, OLúWA sá à ti ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ.” Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, “Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan an kí a sì bi í” Wọ́n sì pe Rebeka wọ́n sì bi í, wí pé, “Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ.” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ.” Wọ́n sì gbà kí Rebeka àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Abrahamu àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ máa lọ. Wọ́n sì súre fún Rebeka, wọn sì wí fun un pé, “Ìwọ ni arábìnrin wa, ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó ni ẹnu ibodè ọ̀tá wọn.” Nígbà náà ni Rebeka àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rebeka, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Isaaki sì ń ti ọ̀nà kànga Lahai-Roi bọ, nítorí ìhà gúúsù ni ó ń gbé. Isaaki sì jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àṣàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ìbákasẹ tí ń bọ̀ wá. Rebeka pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Isaaki. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ìbákasẹ, Ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀. Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Isaaki ohun gbogbo tí ó ti ṣe. Nígbà náà ni Isaaki mú Rebeka wọ inú àgọ́ ìyá rẹ̀, Sara, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Isaaki lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀.