Gẹn 24:3-4
Gẹn 24:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé: Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi.
Pín
Kà Gẹn 24Gẹn 24:3-4 Yoruba Bible (YCE)
n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé, ṣugbọn o óo lọ sí ìlú mi, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi, láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”
Pín
Kà Gẹn 24Gẹn 24:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ OLúWA Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé. Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”
Pín
Kà Gẹn 24