Gẹn 24:28-67

Gẹn 24:28-67 Bibeli Mimọ (YBCV)

Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀. Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga. O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na. O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ. Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀. A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi. O si wipe, Ọmọ-ọdọ Abrahamu li emi iṣe. OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ. Sara, aya oluwa mi, si bí ọmọ kan fun oluwa mi nigbati on (Sara) gbó tán: on li o si fi ohun gbogbo ti o ni fun. Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé: Bikoṣe ki iwọ ki o lọ si ile baba mi, ati si ọdọ awọn ibatan mi, ki o si fẹ́ aya fun ọmọ mi. Emi si wi fun oluwa mi pe, Bọya obinrin na ki yio tẹle mi. O si wi fun mi pe, OLUWA, niwaju ẹniti emi nrìn, yio rán angeli rẹ̀ pelu rẹ, yio si mu ọ̀na rẹ dara; iwọ o si fẹ́ aya fun ọmọ mi lati ọdọ awọn ibatan mi, ati lati inu ile baba mi: Nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ninu ibura mi yi, nigbati iwọ ba de ọdọ awọn ibatan mi; bi nwọn kò ba si fi ẹnikan fun ọ, ọrùn rẹ yio si mọ́ kuro ninu ibura mi. Emi si de si ibi kanga loni, mo si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, bi iwọ ba mu ọ̀na àjo mi ti mo nlọ nisisiyi dara: Kiyesi i, mo duro li ẹba kanga omi; ki o si ṣẹ, pe nigbati wundia na ba jade wá ipọn omi, ti mo ba si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi li omi diẹ ki emi mu lati inu ladugbo rẹ; Ti o si wi fun mi pe, Iwọ mu, emi o si pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu: ki on na ki o ṣe obinrin ti OLUWA ti yàn fun ọmọ oluwa mi. Ki emi ki o si tó wi tán li ọkàn mi, kiyesi i, Rebeka jade de ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀; o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o pọn omi: emi si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi mu omi. O si yara, o si sọ ladugbo rẹ̀ kalẹ kuro li ejika rẹ̀, o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu; bẹ̃li emi mu, o si fi fun awọn ibakasiẹ mu pẹlu. Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀. Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá. Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi. Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ. Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi. O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA. Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀. Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi. Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ. On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ. Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀. Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ. Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ. Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn. Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ. Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé. Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá. Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ. Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀. Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki. Isaaki si mu u wá si inu agọ́ Sara, iya rẹ̀, o si mu Rebeka, o di aya rẹ̀; o si fẹ́ ẹ; a si tu Isaaki ninu lẹhin ikú iya rẹ̀.

Gẹn 24:28-67 Yoruba Bible (YCE)

Ọmọbinrin náà bá sáré lọ sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀. Rebeka ní arakunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Labani. Labani yìí ni ó sáré lọ bá ọkunrin náà ní ìdí kànga. Lẹ́yìn tí ó rí òrùka ati ẹ̀gbà ọwọ́ lọ́wọ́ arabinrin rẹ̀, tí ó sì ti gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkunrin náà sọ fún òun, ó lọ bá ọkunrin náà níbi tí ó dúró sí lẹ́bàá kànga pẹlu àwọn ràkúnmí rẹ̀. Labani sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé, ìwọ ẹni tí OLUWA bukun. Èéṣe tí o fi dúró níta gbangba? Mo ti tọ́jú ilé, mo sì ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún àwọn ràkúnmí rẹ.” Ọkunrin náà bá wọlé, Labani sì tú gàárì àwọn ràkúnmí rẹ̀, ó fi koríko ati oúnjẹ fún wọn. Ó fún un ní omi láti fi ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ẹsẹ̀ àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún un pé kí ó jẹ, ṣugbọn ó wí pé, “N kò ní jẹun títí n óo fi jíṣẹ́ tí wọ́n rán mi.” Labani dáhùn, ó ní, “À ń gbọ́.” Ọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Iranṣẹ Abrahamu ni mí, OLUWA ti bukun oluwa mi lọpọlọpọ, ó sì ti di eniyan ńlá. OLUWA ti fún un ní ọpọlọpọ mààlúù ati agbo ẹran, ọpọlọpọ fadaka ati wúrà, ọpọlọpọ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ati ọpọlọpọ ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Sara, aya oluwa mi bí ọmọkunrin kan fún un lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ọmọ yìí sì ni oluwa mi fi ohun gbogbo tí ó ní fún. Oluwa mi mú mi búra pé n kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí òun ń gbé. Ó ni mo gbọdọ̀ wá síhìn-ín, ní ilé baba òun ati sọ́dọ̀ àwọn ẹbí òun láti fẹ́ aya fún ọmọ òun. Mo sì bi oluwa mi nígbà náà pé, ‘bí obinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá ńkọ́?’ Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, ‘OLUWA náà tí òun ń fi gbogbo ayé òun sìn yóo rán angẹli rẹ̀ sí mi, yóo sì ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ó ní, mo ṣá gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ òun láàrin àwọn eniyan òun ati ní ilé baba òun. Nígbà náà ni ọrùn mi yóo tó mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú fún òun. Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ìbátan òun, tí wọ́n bá kọ̀, tí wọn kò jẹ́ kí ọmọbinrin wọn bá mi wá, ọrùn mi yóo mọ́ kúrò ninu ìbúra tí mo bú.’ “Lónìí, bí mo ti dé ìdí kànga tí ó wà lẹ́yìn ìlú, bẹ́ẹ̀ ni mo gbadura sí Ọlọrun, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, bí ó bá jẹ́ pé o ti ṣe ọ̀nà mi ní rere nítòótọ́, bí mo ti dúró nídìí kànga yìí, ọmọbinrin tí ó bá wá pọnmi, tí mo bá sì sọ fún pé, jọ̀wọ́, fún mi lómi mu ninu ìkòkò omi rẹ, tí ó bá wí fún mi pé, “Omi nìyí, mu, n óo sì pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu”, nígbà náà ni n óo mọ̀ pé òun ni obinrin náà tí ìwọ OLUWA ti yàn láti jẹ́ aya ọmọ oluwa mi.’ Kí n tó dákẹ́ adura mi, Rebeka yọ pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó sì pọnmi. Mo bá wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi lómi mu.’ Kíá ni ó sọ ìkòkò omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, tí ó sì wí pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu.’ Mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí mi lómi mu pẹlu. Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́. Nígbà náà ni mo tẹríba, mo sì sin OLUWA, mo yin OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi lógo, ẹni tí ó tọ́ mi sí ọ̀nà tààrà láti wá fẹ́ ọmọ ẹbí oluwa mi fún ọmọ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ sọ fún mi bí ẹ óo bá ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu oluwa mi tabi ẹ kò ní ṣe ẹ̀tọ́, kí n lè mọ̀ bí n óo ṣe rìn.” Labani ati Betueli dáhùn pé, “Ati ọ̀dọ̀ OLUWA ni nǹkan yìí ti wá, àwa kò sì ní sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́. Rebeka alára nìyí níwájú rẹ yìí, máa mú un lọ kí ó sì di aya ọmọ oluwa rẹ, bí OLUWA ti wí.” Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA. Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu. Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.” Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!” Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” Wọ́n bá pe Rebeka, wọ́n bi í pé, “Ṣé o óo máa bá ọkunrin yìí lọ?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ.” Wọ́n bá gbà pé kí Rebeka arabinrin wọn máa lọ, pẹlu olùtọ́jú rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, pẹlu àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá. Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.” Rebeka ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ bá gun ràkúnmí, wọ́n tẹ̀lé ọkunrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni iranṣẹ náà ṣe mú Rebeka lọ. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Isaaki ti wá láti Beeri-lahai-roi, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nẹgẹbu. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀. Ojú tí Rebeka náà gbé sókè, ó rí Isaaki, ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkúnmí. Ó bi iranṣẹ Abrahamu náà pé, “Ta ni ó ń rìn ninu pápá lọ́ọ̀ọ́kán tí ó ń bọ̀ wá pàdé wa yìí?” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Olúwa mi ni.” Rebeka bá mú ìbòjú rẹ̀, ó dà á bojú. Nígbà tí wọ́n pàdé Isaaki, iranṣẹ náà ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un. Isaaki bá mú Rebeka wọ inú àgọ́ Sara ìyá rẹ̀, Rebeka sì di aya rẹ̀, Isaaki sì fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà yìí ni Isaaki kò tó ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́.

Gẹn 24:28-67 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọmọbìnrin náà sì sáré, ó sì lọ sọ ohun gbogbo wọ̀nyí fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀. Rebeka ní arákùnrin tí ń jẹ́ Labani; Labani sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò. Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ìbákasẹ wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun omi. Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún OLúWA, Èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ìbákasẹ rẹ.” Ọkùnrin náà sì bá Labani lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ìbákasẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn. Wọ́n sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo ní í sọ.” Labani sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.” Nítorí náà, ó wí pé, “ìránṣẹ́ Abrahamu ni èmi. OLúWA sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin àti ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Sara aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní. Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé, Ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrín àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi.’ “Mo sì bí olúwa mi léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá ńkọ́?’ “Ó sì dáhùn wí pé, ‘OLúWA, níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe àṣeyọrí ní ìrìnàjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ìbátan mi, àti láàrín àwọn ìdílé baba mi. Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi (gẹ́gẹ́ bí mo tí wí), nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí.’ “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo wí pé, ‘OLúWA Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, bí ìwọ bá fẹ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lórí ohun tí mo bá wá yìí, Wò ó, mo dúró ní ẹ̀bá ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúńdíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ,” tí ó bá sì wí fún mi pé, “Mu ún, èmi yóò sì tún pọn omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú,” Jẹ́ kí ẹni náà jẹ́ ẹni tí OLúWA yàn fún ọmọ Abrahamu, olúwa mi.’ “Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rebeka jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi. Mo sì wí fun un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu.’ “Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ìbákasẹ rẹ mu pẹ̀lú.’ Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ìbákasẹ mi mu pẹ̀lú. “Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Ọmọ ta ní ìwọ í ṣe?’ “Ó sì wí fún mi pé, ‘ọmọbìnrin Betueli tí í ṣe ọmọ Nahori ni òun, Milka sì ni ìyá òun.’ “Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ náà si ní ọwọ́. Èmi sì tẹríba, mo sì wólẹ̀ fún OLúWA, mó sì fi ìbùkún fún Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, ẹni tí ó mú mi tọ ọ̀nà títọ́ láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi mú wá fún ọmọ rẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ń le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí.” Labani àti Betueli sì dáhùn pé, “Lọ́dọ̀ OLúWA ni èyí ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ. Rebeka nìyí, mú un kí ó máa lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí OLúWA ti fẹ́.” Nígbà tí ọmọ ọ̀dọ̀ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú OLúWA. Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rebeka, ó fún arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà ni òun àti àwọn ọkùnrin tí ó bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, tí wọn sì sùn níbẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó wí pé, “Ẹ rán mi padà lọ sí ọ̀dọ̀ olúwa mi.” Ṣùgbọ́n arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ fèsì pé, “A fẹ́ kí Rebeka wà pẹ̀lú wa fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá sí i, lẹ́yìn èyí, ìwọ le máa mu lọ.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá mi dúró, OLúWA sá à ti ṣe ọ̀nà mi ní rere. Ẹ rán mi lọ, kí èmi kí ó le è tọ olúwa à mi lọ.” Nígbà náà ni wọ́n sọ pé, “Jẹ́ kí a pe ọmọ náà gan an kí a sì bi í” Wọ́n sì pe Rebeka wọ́n sì bi í, wí pé, “Ṣe ìwọ yóò bá ọkùnrin yìí lọ.” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò lọ.” Wọ́n sì gbà kí Rebeka àti olùtọ́jú rẹ̀, pẹ̀lú ìránṣẹ́ Abrahamu àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ máa lọ. Wọ́n sì súre fún Rebeka, wọn sì wí fun un pé, “Ìwọ ni arábìnrin wa, ìwọ yóò di ìyá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Ǹjẹ́ kí àwọn irú-ọmọ rẹ kí ó ni ẹnu ibodè ọ̀tá wọn.” Nígbà náà ni Rebeka àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ múra, wọn sì gun àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì bá ọkùnrin náà padà lọ. Ìránṣẹ́ náà sì mú Rebeka, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Isaaki sì ń ti ọ̀nà kànga Lahai-Roi bọ, nítorí ìhà gúúsù ni ó ń gbé. Isaaki sì jáde lọ sí oko ni ìrọ̀lẹ́ láti ṣe àṣàrò, bí ó sì ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ìbákasẹ tí ń bọ̀ wá. Rebeka pẹ̀lú sì gbójú sókè, ó sì rí Isaaki. Ó sọ̀kalẹ̀ lórí ìbákasẹ, Ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀. Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà ròyìn fún Isaaki ohun gbogbo tí ó ti ṣe. Nígbà náà ni Isaaki mú Rebeka wọ inú àgọ́ ìyá rẹ̀, Sara, ó sì di aya rẹ̀, ó sì fẹ́ràn rẹ̀; ó sì jẹ́ ìtùnú fún Isaaki lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀.