Gẹn 24:1-16

Gẹn 24:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo. Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi; Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé: Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi. Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá? Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá. Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀. Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi. Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori. O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi. O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi. Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi: Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi. O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀. Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke.

Gẹn 24:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Abrahamu ti darúgbó, Ọlọrun sì ti bukun un ní gbogbo ọ̀nà. Abrahamu sọ fún iranṣẹ rẹ̀ tí ó dàgbà jù ninu ilé rẹ̀, ẹni tí í ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó ní, pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi, n óo sì mú kí o búra ní orúkọ OLUWA Ọlọrun ọ̀run ati ayé, pé o kò ní fẹ́ aya fún ọmọ mi lára àwọn ọmọbinrin ará Kenaani tí mò ń gbé, ṣugbọn o óo lọ sí ìlú mi, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi, láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Bí ọmọbinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí, ṣé kí n mú ọmọ rẹ pada sí ilẹ̀ tí o ti wá síhìn-ín?” Abrahamu dáhùn pé, “Rárá o! O kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi pada sibẹ. OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. Ṣugbọn bí obinrin náà bá kọ̀ tí kò tẹ̀lé ọ, nígbà náà ọrùn rẹ yóo mọ́ ninu ìbúra tí o búra fún mi, ṣá má ti mú ọmọ mi pada sibẹ.” Iranṣẹ náà bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ abẹ́ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, ó sì búra láti ṣe ohun tí Abrahamu pa láṣẹ fún un. Iranṣẹ náà mú mẹ́wàá ninu àwọn ràkúnmí oluwa rẹ̀, ó gba oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn àtàtà lọ́wọ́ oluwa rẹ̀, ó jáde lọ sí ilẹ̀ Mesopotamia, sí ìlú Nahori. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ní déédé ìgbà tí àwọn obinrin máa ń jáde lọ pọn omi, ó mú kí àwọn ràkúnmí rẹ̀ kúnlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá kànga kan, ó sì gbadura báyìí pé “Ìwọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, jọ̀wọ́, ṣe ọ̀nà mi ní rere lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, oluwa mi. Bí mo ti dúró lẹ́bàá kànga yìí, tí àwọn ọdọmọbinrin ìlú yìí sì ń jáde wá láti pọn omi, jẹ́ kí ọmọbinrin tí mo bá sọ fún pé jọ̀wọ́ sọ ìkòkò omi rẹ kalẹ̀ kí o fún mi ní omi mu, tí ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo sì fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹlu,’ jẹ́ kí olúwarẹ̀ jẹ́ ẹni náà tí o yàn fún Isaaki, iranṣẹ rẹ. Èyí ni n óo fi mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí oluwa mi.” Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu. Arẹwà wundia ni Rebeka, kò sì tíì mọ ọkunrin. Bí ó ti dé, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó pọn omi rẹ̀, ó sì jáde.

Gẹn 24:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Abrahamu sì ti di arúgbó ní àkókò yìí, OLúWA sì ti bùkún fún un ni gbogbo ọ̀nà, Abrahamu wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi. Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ OLúWA Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé. Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.” Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ńkọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?” Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” “OLúWA, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Abrahamu olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà. Ìránṣẹ́ náà sì mú ìbákasẹ mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Naharaimu, sí ìlú Nahori, Ó sì mú àwọn ìbákasẹ náà kúnlẹ̀ nítòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi. Ó sì gbàdúrà wí pé, “OLúWA, Ọlọ́run Abrahamu olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Abrahamu olúwa mi. Kíyèsi i, mo dúró ní ẹ̀bá kànga omi yìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ń jáde wá pọn omi. Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘mu ún, èmi ó sì fún àwọn ìbákasẹ rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Isaaki. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.” Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rebeka dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Betueli ni. Betueli yìí ni Milka bí fún Nahori arákùnrin Abrahamu. Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúńdíá ni, kò sì tí ì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi.