Gẹn 22:13-14
Gẹn 22:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀. Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i.
Gẹn 22:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Bí Abrahamu ti gbé orí sókè, tí ó wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí àgbò kan tí ó fi ìwo kọ́ pàǹtí. Ó lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.”
Gẹn 22:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, OLúWA yóò pèsè (Jehofah Jire). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè OLúWA, ni a ó ti pèsè.”