Gẹn 22:10-12
Gẹn 22:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Abrahamu si nawọ rẹ̀, o si mu ọbẹ na lati dúmbu ọmọ rẹ̀. Angeli OLUWA nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: o si dahùn pe, Emi niyi. O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo.
Gẹn 22:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Abrahamu nawọ́ mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn angẹli OLUWA pè é láti òkè ọ̀run, ó ní, “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.”
Gẹn 22:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n angẹli OLúWA ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Angẹli OLúWA sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”