Gẹn 22:1-18

Gẹn 22:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhin nkan wọnyi ni Ọlọrun dan Abrahamu wò, o si wi fun u pe, Abrahamu: on si dahùn pe, Emi niyi. O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ. Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãrì, o si mu meji ninu awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati Isaaki, ọmọ rẹ̀, o si là igi fun ẹbọ sisun na, o si dide, o si lọ si ibi ti Ọlọrun sọ fun u. Ni ijọ́ kẹta Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o ri ibẹ̀ na li okere. Abrahamu si wi fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, pe, Ẹnyin joko nihin pẹlu kẹtẹkẹtẹ; ati emi ati ọmọ yi yio lọ si ọhùn ni, a o si gbadura, a o si tun pada tọ̀ nyin wá. Abrahamu si mu igi ẹbọ sisun na, o si dì i rù Isaaki, ọmọ rẹ̀; o si mu iná li ọwọ́ rẹ̀, ati ọbẹ; awọn mejeji si jùmọ nlọ. Isaaki si sọ fun Abrahamu baba rẹ̀, o si wipe, Baba mi: on si wipe, Emi niyi, ọmọ mi. On si wipe, Wò iná on igi; ṣugbọn nibo li ọdọ-agutan ẹbọ sisun na gbé wà? Abrahamu si wipe, Ọmọ mi, Ọlọrun tikalarẹ̀ ni yio pèse ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun: bẹ̃li awọn mejeji jùmọ nlọ. Nwọn si de ibi ti Ọlọrun ti wi fun u; Abrahamu si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si to igi rere, o si dì Isaaki ọmọ rẹ̀, o si dá a bulẹ li ori pẹpẹ lori igi na. Abrahamu si nawọ rẹ̀, o si mu ọbẹ na lati dúmbu ọmọ rẹ̀. Angeli OLUWA nì si kọ si i lati ọrun wá, o wipe, Abrahamu, Abrahamu: o si dahùn pe, Emi niyi. O si wipe, Máṣe fọwọkàn ọmọde nì, bẹ̃ni iwọ kó gbọdọ ṣe e ni nkan: nitori nisisiyi emi mọ̀ pe iwọ bẹ̀ru Ọlọrun, nigbati iwọ kò ti dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo. Abrahamu si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, lẹhin rẹ̀, àgbo kan ti o fi iwo rẹ̀ há ni pantiri: Abrahamu si lọ o mu àgbo na, o si fi i rubọ sisun ni ipò ọmọ rẹ̀. Abrahamu si pè orukọ ibẹ̀ na ni Jehofajire: bi a ti nwi titi di oni yi, Li oke OLUWA li a o gbé ri i. Angeli OLUWA nì si kọ si Abrahamu lati ọrun wá lẹrinkeji, O si wipe, Emi tikalami ni mo fi bura, li OLUWA wi, nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si dù mi li ọmọ rẹ, ọmọ rẹ na kanṣoṣo: Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn; Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.

Gẹn 22:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, Ọlọrun dán Abrahamu wò, ó ní, “Abrahamu!” Abrahamu dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.” Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu. Ní ọjọ́ kẹta, bí Abrahamu ti wo ọ̀kánkán, ó rí ibi tí Ọlọrun júwe fún un ní òkèèrè. Abrahamu bá sọ fún àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e, ó ní, “Ẹ dúró ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ níhìn-ín, èmi ati ọmọ yìí yóo rìn siwaju díẹ̀, láti lọ sin Ọlọ́run, a óo sì pada wá bá yín.” Abrahamu gbé igi ẹbọ sísun náà lé Isaaki, ọmọ rẹ̀ lórí, ó mú ọ̀bẹ ati iná lọ́wọ́. Àwọn mejeeji jọ ń lọ. Isaaki bá pe Abrahamu, baba rẹ̀, ó ní, “Baba mi.” Baba rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Kí ni, ọmọ mi?” Isaaki ní, “Wò ó, a rí iná ati igi, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun dà?” Abrahamu dá a lóhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni yóo pèsè, àgbò tí a óo fi rú ẹbọ sísun náà.” Àwọn mejeeji tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ọlọrun júwe fún Abrahamu, ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó to igi sórí pẹpẹ náà, ó di Isaaki ọmọ rẹ̀ tọwọ́ tẹsẹ̀, ó bá gbé e ka orí igi lórí pẹpẹ tí ó tẹ́. Abrahamu nawọ́ mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn angẹli OLUWA pè é láti òkè ọ̀run, ó ní, “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Èmi nìyí.” Angẹli náà wí fún un pé, “Má ṣe pa ọmọ náà rárá, má sì ṣe é ní ohunkohun, nítorí pé nisinsinyii mo mọ̀ dájú pé o bẹ̀rù Ọlọrun, nígbà tí o kò kọ̀ láti fi ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o bí rúbọ sí èmi Ọlọrun.” Bí Abrahamu ti gbé orí sókè, tí ó wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí àgbò kan tí ó fi ìwo kọ́ pàǹtí. Ó lọ mú àgbò náà, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. Nítorí náà ni Abrahamu ṣe sọ ibẹ̀ ní “OLUWA yóo pèsè,” bí wọ́n ti ń wí títí di òní, pé, “Ní orí òkè OLUWA ni yóo ti pèsè.” Angẹli OLUWA tún pe Abrahamu láti òkè ọ̀run ní ìgbà keji, ó ní, “Mo fi ara mi búra pé nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ kan ṣoṣo, n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà. Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”

Gẹn 22:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moriah, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.” Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè, Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.” Abrahamu sì gbé igi ẹbọ sísun náà ru Isaaki, òun fúnrarẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ, Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?” Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ. Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà. Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n angẹli OLúWA ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Angẹli OLúWA sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.” Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, OLúWA yóò pèsè (Jehofah Jire). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè OLúWA, ni a ó ti pèsè.” Angẹli OLúWA sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. Ó sì wí pé, OLúWA wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, Nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”