Gẹn 21:1-34

Gẹn 21:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si bẹ̀ Sara wò bi o ti wi, OLUWA si ṣe fun Sara bi o ti sọ. Sara si loyun, o si bí ọmọkunrin kan fun Abrahamu li ogbologbo rẹ̀, li akokò igbati Ọlọrun dá fun u. Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u. Abrahamu si kọ Isaaki ọmọ rẹ̀ ni ilà, nigbati o di ọmọ ijọ́ mẹjọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. Abrahamu si jẹ ẹni ọgọrun ọdún, nigbati a bí Isaaki ọmọ rẹ̀ fun u. Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi. O si wipe, Tani iba wi fun Abrahamu pe, Sara yio fi ọmú fun ọmọ mu? mo sá bí ọmọ kan fun u li ogbologbo rẹ̀. Ọmọ na si dàgba, a si já a li ẹnu ọmú: Abrahamu si sè àse nla li ọjọ́ na ti a já Isaaki li ẹnu ọmú. Sara si ri ọmọ Hagari, ara Egipti, ti o bí fun Abrahamu, o nfi i rẹrin. Nitorina li o ṣe wi fun Abrahamu pe, Lé ẹrubirin yi jade ti on ti ọmọ rẹ̀: nitoriti ọmọ ẹrubirin yi ki yio ṣe arole pẹlu Isaaki, ọmọ mi. Ọrọ yi si buru gidigidi li oju Abrahamu nitori ọmọ rẹ̀. Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ. Ati ọmọ ẹrubirin na pẹlu li emi o sọ di orilẹ-ède, nitori irú-ọmọ rẹ ni iṣe. Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o mu àkara ati ìgo omi kan, o fi fun Hagari, o gbé e lé e li ejika, ati ọmọ na, o si lé e jade: on si lọ, o nrìn kakiri ni ijù Beer-ṣeba. Omi na si tán ninu ìgo, o si sọ̀ ọmọ na si abẹ ìgboro kan. O si lọ, o joko kọju si i, li ọ̀na jijìn rére, o tó bi itafasi kan: nitori ti o wipe, Ki emi má ri ikú ọmọ na. O si joko kọju si i, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o nsọkun. Ọlọrun si gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na: angeli Ọlọrun si pè Hagari lati ọrun wá, o bi i pe, Kili o ṣe ọ, Hagari? máṣe bẹ̀ru; nitori ti Ọlọrun ti gbọ́ ohùn ọmọdekunrin na nibiti o gbé wà. Dide, gbé ọmọdekunrin na, ki o si dì i mu; nitori ti emi o sọ ọ di orilẹ-ède nla. Ọlọrun si ṣí i li oju, o si ri kanga omi kan; o lọ, o si pọnmi kún ìgo na, o si fi fun ọmọdekunrin na mu. Ọlọrun si wà pẹlu ọmọdekunrin na; o si dàgba, o si joko ni ijù, o di tafatafa. O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá. O si ṣe li akokò na, ni Abimeleki ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, wi fun Abrahamu pe, Ọlọrun pẹlu rẹ ni gbogbo ohun ti iwọ nṣe. Njẹ nisisiyi fi Ọlọrun bura fun mi nihinyi pe iwọ ki yio ṣe ẹ̀tan si mi, tabi si ọmọ mi, tabi si ọmọ-ọmọ mi: ṣugbọn gẹgẹ bi iṣeun ti mo ṣe si ọ, bẹ̃ni iwọ o si ṣe si mi, ati si ilẹ ti iwọ ti ṣe atipo ninu rẹ̀. Abrahamu si wipe, emi o bura. Abrahamu si ba Abimeleki wi nitori kanga omi kan, ti awọn ọmọ-ọdọ Abimeleki fi agbara gbà. Abimeleki si wipe, emi kò mọ̀ ẹniti o ṣe nkan yi: bẹ̃ni iwọ kò sọ fun mi, bẹ̃li emi kò gbọ́, bikoṣe loni. Abrahamu si mu agutan, ati akọmalu, o fi wọn fun Abimeleki; awọn mejeji si dá majẹmu. Abrahamu si yà abo ọdọ-agutan meje ninu agbo si ọ̀tọ fun ara wọn. Abimeleki si bi Abrahamu pe, kili a le mọ̀ abo ọdọ-agutan meje ti iwọ yà si ọ̀tọ fun ara wọn yi si? O si wipe, nitori abo ọdọ-agutan meje yi ni iwọ o gbà lọwọ mi, ki nwọn ki o le ṣe ẹrí mi pe, emi li o wà kanga yi. Nitorina li o ṣe pè ibẹ̀ na ni Beer-ṣeba; nitori nibẹ̀ li awọn mejeji gbé bura. Bẹ̃ni nwọn si dá majẹmu ni Beer-ṣeba: nigbana li Abimeleki dide, ati Fikoli, olori ogun rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilẹ awọn ara Filistia. Abrahamu si lọ́ igi tamariski kan ni Beer-ṣeba, nibẹ̀ li o si pè orukọ OLUWA, Ọlọrun Aiyeraiye. Abrahamu si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọjọ́ pupọ̀.

Gẹn 21:1-34 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un. Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki. Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un. Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.” Ó tún wí pé, “Ta ni ó lè sọ fún Abrahamu pé Sara yóo fún ọmọ lọ́mú? Sibẹsibẹ mo bí ọmọ fún un nígbà tí ó ti di arúgbó.” Ọmọ náà dàgbà, ó sì já lẹ́nu ọmú, Abrahamu sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí ọmọ náà já lẹ́nu ọmú. Ní ọjọ́ kan, Sara rí ọmọ tí Hagari, ará Ijipti bí fún Abrahamu, níbi tí ó ti ń bá Isaaki, ọmọ rẹ̀, ṣeré. Sara bá pe Abrahamu, ó sọ fún un pé, “Lé ẹrubinrin yìí jáde pẹlu ọmọ rẹ̀, nítorí pé ọmọ ẹrubinrin yìí kò ní jẹ́ àrólé pẹlu Isaaki ọmọ mi.” Ọ̀rọ̀ yìí kò dùn mọ́ Abrahamu ninu nítorí Iṣimaeli, ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun wí fún Abrahamu pé, “Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọmọ yìí ati ti ẹrubinrin rẹ, ohunkohun tí Sara bá wí fún ọ ni kí o ṣe, nítorí pé orúkọ Isaaki ni wọn yóo fi máa pe atọmọdọmọ rẹ. N óo sọ ọmọ ẹrubinrin náà di orílẹ̀ èdè ńlá pẹlu, nítorí ọmọ rẹ ni òun náà.” Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó mú oúnjẹ ati omi sinu ìgò aláwọ kan, ó dì wọ́n fún Hagari, ó kó wọn kọ́ ọ léjìká, ó fa ọmọ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó ní kí wọn ó jáde kúrò nílé. Hagari jáde nílé, ó bá ń rìn káàkiri ninu aginjù Beeriṣeba. Nígbà tí omi tán ninu ìgò aláwọ náà, Hagari fi ọmọ náà sílẹ̀ lábẹ́ igbó ṣúúrú kan tí ó wà níbẹ̀. Ó lọ jókòó ní òkèèrè, ó takété sí i, ó tó ìwọ̀n ibi tí ọfà tí eniyan bá ta lè balẹ̀ sí, nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “Má jẹ́ kí n wo àtikú ọmọ mi.” Bí ó ṣe jókòó tí ó takété sí ọmọ náà, ọmọ fi igbe ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ọlọrun gbọ́ igbe ọmọ náà, angẹli Ọlọrun bá ké sí Hagari láti ọ̀run wá, ó bi í pé, “Kí ni ó ń dààmú ọkàn rẹ, Hagari? Má bẹ̀rù, nítorí Ọlọrun ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí ó wà. Dìde, lọ gbé e, kí o sì rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún, nítorí n óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ọlọrun bá la Hagari lójú, ó rí kànga kan, ó rọ omi kún inú ìgò aláwọ rẹ̀, ó sì fún ọmọdekunrin náà mu. Ọlọrun wà pẹlu ọmọ náà, ó dàgbà, ó ń gbé ninu aginjù, ó sì mọ ọfà ta tóbẹ́ẹ̀ tí ó di atamátàsé. Ó ń gbé inú aginjù Parani, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ aya fún un ní ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sọ fún Abrahamu pé, “Ọlọrun wà pẹlu rẹ ninu ohun gbogbo tí ò ń ṣe. Nítorí náà, fi Ọlọrun búra fún mi níhìn-ín yìí, pé o kò ní hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi, tabi sí àwọn ọmọ mi, tabi sí ìran mi, ṣugbọn bí mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà yóo jẹ́ olóòótọ́ sí mi ati sí ilẹ̀ tí o ti ń ṣe àtìpó.” Abrahamu bá sọ pé òun yóo búra. Abrahamu rò fún Abimeleki bí àwọn iranṣẹ Abimeleki ti fi ipá gba kànga omi kan lọ́wọ́ rẹ̀, Abimeleki bá dá a lóhùn, ó ní “N kò mọ ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, o kò sọ fún mi, n kò gbọ́ nǹkankan nípa rẹ̀, àfi bí o ti ń sọ yìí.” Abrahamu fún Abimeleki ní aguntan ati mààlúù, àwọn mejeeji bá jọ dá majẹmu. Abrahamu ya abo ọmọ aguntan meje ninu agbo rẹ̀ sọ́tọ̀. Abimeleki bá bi Abrahamu, ó ní, “Kí ni ìtumọ̀ abo ọmọ aguntan meje tí o yà sọ́tọ̀ wọnyi?” Abrahamu dá a lóhùn pé, “Gba abo ọmọ aguntan meje wọnyi lọ́wọ́ mi, kí o lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Beeriṣeba, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn mejeeji ti búra. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe dá majẹmu ní Beeriṣeba. Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sì pada lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Abrahamu gbin igi tamarisiki kan sí Beeriṣeba, ó sì ń sin OLUWA Ọlọrun ayérayé níbẹ̀. Abrahamu gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ìgbà pípẹ́.

Gẹn 21:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, OLúWA sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un. Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki. Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki. Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.” Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.” Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá. Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.” Ọ̀rọ̀ náà sì ba Abrahamu lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sá à ni Iṣmaeli i ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun Abrahamu pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Sara wí fún ọ, nítorí nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀. Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.” Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Hagari, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Beerṣeba. Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó. Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí. Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dìímú (tù ú nínú) nítorí èmi yóò sọ ọmọ náà di orílẹ̀-èdè ńlá.” Ọlọ́run sì ṣí ojú Hagari, ó sì rí kànga kan, ó lọ síbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà. Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá. Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.” Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.” Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.” Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú. Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀. Abimeleki sì béèrè lọ́wọ́ Abrahamu pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.” Ó dalóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra. Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Beerṣeba yìí, ni Abimeleki àti Fikoli olórí ogun rẹ̀ padà sí ilẹ̀ àwọn ará Filistini. Abrahamu lọ́ igi tamariski kan sí Beerṣeba, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ OLúWA Ọlọ́run ayérayé. Abrahamu sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọjọ́ pípẹ́.