Gẹn 20:1-18

Gẹn 20:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri. Abrahamu sọ fún àwọn ará Gerari pé arabinrin òun ni Sara aya rẹ̀, Abimeleki, ọba Gerari bá ranṣẹ lọ mú Sara. Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.” Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí? Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.” Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án. Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.” Abimeleki yára dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ jọ, ó ro gbogbo nǹkan wọnyi fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Abimeleki bá pe Abrahamu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí o fi ti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí sí èmi ati ìjọba mi lọ́rùn? Ohun tí o ṣe sí mi yìí kò dára rárá!” Ó bi Abrahamu pé, “Kí ni èrò rẹ gan-an, tí o fi ṣe ohun tí o ṣe yìí?” Abrahamu dáhùn, ó ní, “Ohun tí ó mú mi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, mo rò pé kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun níhìn-ín rárá ni, ati pé wọn yóo tìtorí aya mi pa mí. Ati pé, arabinrin mi ni nítòótọ́, bí ó ṣe jẹ́ nìyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìyá kan náà ni ó bí wa, ọmọ baba kan ni wá kí ó tó di aya mi. Nígbà tí Ọlọrun mú kí n máa káàkiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Oore kan tí o lè ṣe fún mi nìyí: níbi gbogbo tí a bá dé, wí fún wọn pé, arakunrin rẹ ni mí.’ ” Abimeleki mú aguntan ati mààlúù ati ẹrukunrin ati ẹrubinrin, ó kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara, aya rẹ̀, pada fún un. Abimeleki tún wí fún un pé, “Wo gbogbo ilẹ̀ yìí, èmi ni mo ni ín, yan ibi tí ó bá wù ọ́ láti gbé.” Ó wí fún Sara náà pé, “Mo ti kó ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka fún arakunrin rẹ, èyí ni láti wẹ̀ ọ́ mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ, nisinsinyii, o ti gba ìdáláre lójú gbogbo eniyan.” Abrahamu bá gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun sì wo Abimeleki sàn ati aya rẹ̀ ati àwọn ẹrubinrin rẹ̀, tí wọ́n fi lè bímọ, nítorí pé Ọlọrun ti sé gbogbo àwọn obinrin ilé Abimeleki ninu nítorí Sara, aya Abrahamu.

Gẹn 20:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

ABRAHAMU si ṣí lati ibẹ̀ lọ si ilẹ ìha gusù, o si joko li agbedemeji Kadeṣi on Ṣuri; o si ṣe atipo ni Gerari. Abrahamu si wi niti Sara aya rẹ̀ pe, Arabinrin mi ni: Abimeleki ọba Gerari si ranṣẹ, o si mu Sara. Ṣugbọn Ọlọrun tọ̀ Abimeleki wá li ojuran li oru, o si wi fun u pe, kiyesi i, okú ni iwọ, nitori obinrin ti iwọ mu nì; nitori aya ọkunrin kan ni iṣe. Ṣugbọn Abimeleki kò sunmọ ọ: o si wipe, OLUWA, iwọ o run orilẹ-ède olododo pẹlu? On kọ ló ha wi fun mi pe arabinrin mi ni iṣe? on, obinrin tikalarẹ̀ si wipe, arakunrin mi ni: li otitọ inu ati alaiṣẹ̀ ọwọ́ mi, ni mo fi ṣe eyi. Ọlọrun si wi fun u li ojuran pe, Bẹ̃ni, emi mọ̀ pe li otitọ inu rẹ ni iwọ ṣe eyi; nitorina li emi si ṣe dá ọ duro ki o má ba ṣẹ̀ mi: nitorina li emi kò ṣe jẹ ki iwọ ki o fọwọkàn a. Njẹ nitori na mu aya ọkunrin na pada fun u; woli li on sa iṣe, on o si gbadura fun ọ, iwọ o si yè: bi iwọ kò ba si mu u pada, ki iwọ ki o mọ̀ pe, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo ẹniti o jẹ tirẹ. Nitorina Abimeleki dide ni kutukutu owurọ̀, o si pè gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si wi gbogbo nkan wọnyi li eti wọn: ẹ̀ru si bà awọn enia na gidigidi. Nigbana li Abimeleki pè Abrahamu, o si wi fun u pe, Kili o ṣe si wa yi? ẹ̀ṣẹ kini mo ṣẹ̀ ọ, ti iwọ fi mu ẹ̀ṣẹ nla wá si ori mi, ati si ori ijọba mi? iwọ hùwa si mi ti a ki ba hù. Abimeleki si wi fun Abrahamu pe, Kini iwọ ri, ti iwọ fi ṣe nkan yi? Abrahamu si wipe, Nitoriti mo rò pe, nitõtọ ẹ̀ru Ọlọrun kò sí nihinyi; nwọn o si pa mi nitori aya mi. Ati pẹlupẹlu nitõtọ arabinrin mi ni iṣe, ọmọbinrin baba mi ni, ṣugbọn ki iṣe ọmọbinrin iya mi; o si di aya mi. O si ṣe nigbati Ọlọrun mu mi rìn kiri lati ile baba mi wá, on ni mo wi fun u pe, eyi ni ore rẹ ti iwọ o ma ṣe fun mi; nibikibi ti awa o gbé de, ma wi nipa ti emi pe, arakunrin mi li on. Abimeleki si mu agutan, ati akọmalu, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, o si fi wọn fun Abrahamu, o si mu Sara, aya rẹ̀, pada fun u. Abimeleki si wipe, Kiyesi i, ilẹ mi niyi niwaju rẹ: joko nibiti o wù ọ. O si wi fun Sara pe, Kiyesi i, mo fi ẹgbẹrun ìwọn fadaka fun arakunrin rẹ: kiyesi i, on ni ibojú fun ọ fun gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ, ati niwaju gbogbo awọn ẹlomiran li a da ọ lare. Abrahamu si gbadura si Ọlọrun: Ọlọrun si mu Abimeleki li ara dá, ati aya rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin-ọdọ rẹ̀; nwọn si bimọ. Nitori OLUWA ti sé inu awọn ara ile Abimeleki pinpin, nitori ti Sara, aya Abrahamu.

Gẹn 20:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀. Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ nnì, aya ẹni kan ní íṣe.” Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí? Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.” Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Abimeleki pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.” Abimeleki sì bi Abrahamu pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?” Abrahamu sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi. Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya. Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi: Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ” Nígbà náà ni Abimeleki mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara aya rẹ̀ padà fún un. Abimeleki sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilẹ̀ mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.” Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.” Nígbà náà, Abrahamu gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Abimeleki àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ. Nítorí Ọlọ́run ti sé gbogbo ará ilé Abimeleki nínú nítorí Sara aya Abrahamu.