Gẹn 2:8-25

Gẹn 2:8-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu. Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin. Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà; Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki. Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká. Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate. OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ. OLUWA Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki o ma jẹ: Ṣugbọn ninu igi ìmọ rere ati bururu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kikú ni iwọ o kú. OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀. Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. OLUWA Ọlọrun si mu orun ìjika kùn Adamu, o si sùn: o si yọ ọkan ninu egungun-ìha rẹ̀, o si fi ẹran di ipò rẹ̀: OLUWA Ọlọrun si fi egungun-ìha ti o mu ni ìha ọkunrin na mọ obinrin, o si mu u tọ̀ ọkunrin na wá. Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a o ma pè e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá. Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan. Awọn mejeji si wà ni ìhoho, ati ọkunrin na ati obinrin rẹ̀, nwọn kò si tiju.

Gẹn 2:8-25 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀. Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire. Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin. Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà. Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu. Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate. OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.” Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́. Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ. Ọkunrin náà bá wí pé, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi, ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi; obinrin ni yóo máa jẹ́, nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.” Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo. Ọkunrin náà ati obinrin náà wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

Gẹn 2:8-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. OLúWA Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. Orúkọ èkínní ni Pisoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá (bedeliumu) àti òkúta (óníkìsì) oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). Orúkọ odò kejì ni Gihoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi: òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate. OLúWA Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. OLúWA Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.” OLúWA Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” Lẹ́yìn tí OLúWA Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. Nígbà náà ni OLúWA Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. OLúWA Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá. Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan. Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa