Gẹn 2:8-17
Gẹn 2:8-17 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀. Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire. Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin. Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà. Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu. Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate. OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀. Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.”
Gẹn 2:8-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu. Odò kan si ti Edeni ṣàn wá lati rin ọgbà na; lati ibẹ̀ li o gbé yà, o si di ipa ori mẹrin. Orukọ ekini ni Pisoni: on li eyiti o yi gbogbo ilẹ Hafila ká, nibiti wurà wà; Wurà ilẹ na si dara: nibẹ ni bedeliumu (ojia) wà ati okuta oniki. Orukọ odò keji si ni Gihoni: on na li eyiti o yi gbogbo ilẹ Kuṣi ká. Ati orukọ odò kẹta ni Hiddekeli: on li eyiti nṣàn lọ si ìha ìla-õrùn Assiria. Ati odò kẹrin ni Euferate. OLUWA Ọlọrun si mu ọkunrin na, o si fi i sinu ọgbà Edeni lati ma ro o, ati lati ma ṣọ́ ọ. OLUWA Ọlọrun si fi aṣẹ fun ọkunrin na pe, Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki o ma jẹ: Ṣugbọn ninu igi ìmọ rere ati bururu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitoripe li ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kikú ni iwọ o kú.
Gẹn 2:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. OLúWA Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà. Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. Orúkọ èkínní ni Pisoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá (bedeliumu) àti òkúta (óníkìsì) oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). Orúkọ odò kejì ni Gihoni: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi: òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate. OLúWA Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. OLúWA Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”