Gẹn 2:18-24
Gẹn 2:18-24 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́. Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀. Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ. Ọkunrin náà bá wí pé, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi, ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi; obinrin ni yóo máa jẹ́, nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.” Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo.
Gẹn 2:18-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” Lẹ́yìn tí OLúWA Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. Nígbà náà ni OLúWA Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. OLúWA Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá. Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.” Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.
Gẹn 2:18-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA Ọlọrun si wipe, kò dara ki ọkunrin na ki o nikan ma gbé; emi o ṣe oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun si ti dá ẹranko igbẹ gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun gbogbo; o si mu wọn tọ̀ Adamu wá lati wò orukọ ti yio sọ wọn; orukọkorukọ ti Adamu si sọ olukuluku ẹda alãye, on li orukọ rẹ̀. Adamu si sọ ẹran-ọ̀sin gbogbo, ati ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko igbẹ gbogbo, li orukọ; ṣugbọn fun Adamu a kò ri oluranlọwọ ti o dabi rẹ̀ fun u. OLUWA Ọlọrun si mu orun ìjika kùn Adamu, o si sùn: o si yọ ọkan ninu egungun-ìha rẹ̀, o si fi ẹran di ipò rẹ̀: OLUWA Ọlọrun si fi egungun-ìha ti o mu ni ìha ọkunrin na mọ obinrin, o si mu u tọ̀ ọkunrin na wá. Adamu si wipe, Eyiyi li egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi: Obinrin li a o ma pè e, nitori ti a mu u jade lati ara ọkunrin wá. Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rẹ̀ silẹ, yio si fi ara mọ́ aya rẹ̀: nwọn o si di ara kan.