Gẹn 19:24-26
Gẹn 19:24-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li OLUWA rọ̀jo sulfuri (okuta ina) ati iná lati ọdọ OLUWA lati ọrun wá si ori Sodomu on Gomorra: O si run ilu wọnni, ati gbogbo Pẹtẹlẹ, ati gbogbo awọn ara ilu wọnni, ati ohun ti o hù jade ni ilẹ. Ṣugbọn aya rẹ̀ bojuwò ẹhin lẹhin rẹ̀, o si di ọwọ̀n iyọ̀.
Gẹn 19:24-26 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora, ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀. Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀.
Gẹn 19:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA rọ̀jò iná àti Sulfuru (òkúta iná) sórí Sodomu àti Gomorra—láti ọ̀run lọ́dọ̀ OLúWA wá. Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀.