Gẹn 19:1-38

Gẹn 19:1-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN Angeli meji si wá si Sodomu li aṣalẹ; Loti si joko li ẹnu-bode Sodomu: bi Loti si ti ri wọn, o dide lati pade wọn: o si dojubolẹ; O si wipe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnyin oluwa mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ yà si ile ọmọ-ọdọ nyin, ki ẹ si wọ̀, ki ẹ si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ẹnyin o si dide ni kùtukutu, ki ẹ si ma ba ti nyin lọ. Nwọn si wipe, Ndao; ṣugbọn awa o joko ni igboro li oru oni. O si rọ̀ wọn gidigidi; nwọn si yà tọ̀ ọ, nwọn si wọ̀ inu ile rẹ̀; o si sè àse fun wọn, o si dín àkara alaiwu fun wọn, nwọn si jẹ. Ṣugbọn ki nwọn ki o to dubulẹ, awọn ọkunrin ara ilu na, awọn ọkunrin Sodomu, nwọn yi ile na ká, ati àgba ati ewe, gbogbo enia lati ori igun mẹrẹrin wá. Nwọn si pè Loti, nwọn si bi i pe, Nibo li awọn ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá li alẹ yi wà? mu wọn jade fun wa wá, ki awa ki o le mọ̀ wọn. Loti si jade tọ̀ wọn lọ li ẹnu-ọ̀na, o si sé ilẹkun lẹhin rẹ̀. O si wipe, Arakunrin, emi bẹ̀ nyin, ẹ máṣe hùwa buburu bẹ̃. Kiyesi i nisisiyi, emi li ọmọbinrin meji ti kò ti imọ̀ ọkunrin: emi bẹ̀ nyin, ẹ jẹ ki nmu wọn jade tọ̀ nyin wá, ki ẹnyin ki o si fi wọn ṣe bi o ti tọ́ loju nyin: ṣugbọn awọn ọkunrin wọnyi ṣa ni ki ẹ má ṣe ni nkan; nitorina ni nwọn sa ṣe wá si abẹ orule mi. Nwọn si wipe, Bì sẹhin. Nwọn si tun wipe, Eyiyi wá iṣe atipo, on si fẹ iṣe onidajọ: njẹ iwọ li a o tilẹ ṣe ni buburu jù wọn lọ. Nwọn si rọlù ọkunrin na, ani Loti, nwọn si sunmọ ọ lati fọ́ ilẹkun. Ṣugbọn awọn ọkunrin na nà ọwọ́ wọn, nwọn si fà Loti mọ́ ọdọ sinu ile, nwọn si tì ilẹkun. Nwọn si bù ifọju lù awọn ọkunrin ti o wà li ẹnu-ọ̀na ile na, ati ewe ati àgba: bẹ̃ni nwọn dá ara wọn li agara lati ri ẹnu-ọ̀na. Awọn ọkunrin na si wi fun Loti pe, Iwọ ni ẹnikan nihin pẹlu? ana rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ati ohunkohun ti iwọ ni ni ilu, mu wọn jade kuro nihinyi: Nitori awa o run ibi yi, nitori ti igbe wọn ndi pupọ̀ niwaju OLUWA; OLUWA si rán wa lati run u. Loti si jade, o si sọ fun awọn ana rẹ̀ ọkunrin, ti nwọn gbe awọn ọmọbinrin rẹ̀ ni iyawo, o wipe, Ẹ dide, ẹ jade kuro nihinyi; nitoriti OLUWA yio run ilu yi. Ṣugbọn o dabi ẹlẹtàn loju awọn ana rẹ̀. Nigbati ọ̀yẹ si nla, nigbana li awọn angeli na le Loti ni ire wipe, Dide, mu aya rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ mejeji ti o wà nihin; ki iwọ ki o má ba run ninu ìya ẹ̀ṣẹ ilu yi. Nigbati o si nlọra, awọn ọkunrin na nawọ mu u li ọwọ́, ati ọwọ́ aya rẹ̀, ati ọwọ́ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji; OLUWA sa ṣãnu fun u: nwọn si mu u jade, nwọn si fi i sẹhin odi ilu na. O si ṣe nigbati nwọn mu wọn jade sẹhin odi tan, li o wipe, Sá asalà fun ẹmi rẹ; máṣe wò ẹhin rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe duro ni gbogbo pẹtẹlẹ; sá asalà lọ si ori oke, ki iwọ ki o má ba ṣegbe. Loti si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, oluwa mi: Kiyesi i na, ọmọ-ọdọ rẹ ti ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, iwọ si ti gbe ãnu rẹ ga, ti iwọ ti fi hàn mi ni gbigbà ẹmi mi là; ṣugbọn emi ki yio le salọ si ori oke, ki ibi ki o má ba bá mi nibẹ̀, ki emi ki o má ba kú. Kiyesi i na, ilu yi sunmọ tosi lati sá si, kekere si ni: jọ̃, jẹ ki nsalà si ibẹ, (kekere ha kọ?) ọkàn mi yio si yè. O si wi fun u pe, Wò o, mo gbà fun ọ niti ohun kan yi pẹlu pe, emi ki yio run ilu yi, nitori eyiti iwọ ti sọ. Yara, salà sibẹ̀; nitori emi kò le ṣe ohun kan titi iwọ o fi de ibẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Soari. Orùn là sori ilẹ nigbati Loti wọ̀ ilu Soari. Nigbana li OLUWA rọ̀jo sulfuri (okuta ina) ati iná lati ọdọ OLUWA lati ọrun wá si ori Sodomu on Gomorra: O si run ilu wọnni, ati gbogbo Pẹtẹlẹ, ati gbogbo awọn ara ilu wọnni, ati ohun ti o hù jade ni ilẹ. Ṣugbọn aya rẹ̀ bojuwò ẹhin lẹhin rẹ̀, o si di ọwọ̀n iyọ̀. Abrahamu si dide ni kutukutu owurọ̀, o lọ si ibi ti o gbé duro niwaju OLUWA: O si wò ìha Sodomu on Gomorra, ati ìha gbogbo ilẹ àgbegbe wọnni, o si wò o, si kiyesi i, ẽfin ilẹ na rú soke bi ẽfin ileru. O si ṣe nigbati Ọlọrun run ilu àgbegbe wọnni ni Ọlọrun ranti Abrahamu, o si rán Loti jade kuro lãrin iparun na, nigbati o run ilu wọnni ninu eyiti Loti gbé ti joko. Loti si jade kuro ni Soari: o si ngbé ori oke, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nitoriti o bẹ̀ru ati gbé Soari: o si ngbé inu ihò, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeji. Eyi akọbi si wi fun atẹle pe, Baba wa gbó, kò si sí ọkunrin kan li aiye mọ́ ti yio wọle tọ̀ wa wá gẹgẹ bi iṣe gbogbo aiye. Wá, jẹ ki a mu baba wa mu ọti-waini, awa o si sùn tì i, ki a le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa. Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na: eyi akọbi wọle tọ̀ ọ, o si sùn tì baba rẹ̀; on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. O si ṣe, ni ijọ́ keji, ni ẹgbọn wi fun aburo pe, kiyesi i, emi sùn tì baba mi li oru aná: jẹ ki a si mu u mu ọti-waini li oru yi pẹlu: ki iwọ ki o si wọle, ki o si sùn tì i, ki awa ki o le ni irú-ọmọ lati ọdọ baba wa. Nwọn si mu baba wọn mu ọti-waini li oru na pẹlu: aburo si dide, o si sùn tì i, on kò si mọ̀ igbati o dubulẹ, ati igbati o dide. Bẹ̃li awọn ọmọbinrin Loti mejeji loyun fun baba wọn. Eyi akọ́bi si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Moabu: on ni baba awọn ara Moabu titi di oni. Eyi atẹle, on pẹlu si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Ben-ammi: on ni baba awọn ọmọ Ammoni, titi di oni.

Gẹn 19:1-38 Yoruba Bible (YCE)

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn angẹli meji náà dé ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnubodè ìlú náà. Bí ó ti rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn. Ó ní, “Ẹ̀yin oluwa mi, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yà sí ilé èmi iranṣẹ yín, kí ẹ ṣan ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sùn ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ìdájí ọ̀la, kí ẹ máa bá tiyín lọ.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Ó tì o! ìta gbangba láàrin ìlú ni a fẹ́ sùn.” Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n gidigidi, wọ́n bá yà sí ilé rẹ̀, ó se àsè fún wọn, ó ṣe àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì jẹun. Ṣugbọn kí àwọn àlejò náà tó sùn, gbogbo àwọn ọkunrin ìlú Sodomu ti dé, àtèwe, àtàgbà, gbogbo wọn dé láìku ẹnìkan, wọ́n yí ilé Lọti po. Wọ́n pe Lọti, wọ́n ní, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí wọ́n dé sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí wà? Kó wọn jáde fún wa, a fẹ́ bá wọn lòpọ̀.” Lọti bá jáde sí wọn, ó ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn àlejò sinu ilé, ó bẹ̀ wọ́n pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí. Ẹ wò ó, mo ní àwọn ọmọbinrin meji tí wọn kò tíì mọ ọkunrin, ẹ jẹ́ kí n kó wọn jáde fún yín, kí ẹ ṣe wọ́n bí ó ti wù yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ọkunrin wọnyi sílẹ̀, nítorí pé inú ilé mi ni wọ́n wọ̀ sí.” Wọ́n dáhùn pé, “Yàgò lọ́nà fún wa, ṣebí àjèjì ni ọ́ ní ilẹ̀ yìí? Ta ni ọ́ tí o fi ń sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa? Bí o kò bá ṣọ́ra, a óo ṣe sí ọ ju bí a ti fẹ́ ṣe sí wọn lọ.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ti Lọti mọ́ ara ìlẹ̀kùn títí ìlẹ̀kùn fi fẹ́rẹ̀ já. Àwọn àjèjì náà bá fa Lọti wọlé, wọ́n ti ìlẹ̀kùn, wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkunrin tí wọ́n ṣù bo ìlẹ̀kùn lóde, àtèwe, àtàgbà wọn, wọ́n wá ojú ọ̀nà títí tí agara fi dá wọn. Àwọn àlejò náà pe Lọti, wọ́n sọ fún un pé, “Bí o bá ní ẹnikẹ́ni ninu ìlú yìí, ìbáà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin tabi ọkọ àwọn ọmọ rẹ, tabi ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ tìrẹ ninu ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò níhìn-ín, nítorí pé a ti ṣetán láti pa ìlú yìí run, nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn ará ìlú yìí ti pọ̀ níwájú OLUWA, OLUWA sì ti rán wa láti pa á run.” Lọti bá jáde lọ bá àwọn ọkunrin tí wọ́n fẹ́ àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji sọ́nà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ dìde, ẹ jáde kúrò ninu ìlú yìí nítorí OLUWA fẹ́ pa á run.” Ṣugbọn àwàdà ni ọ̀rọ̀ náà jọ létí wọn. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Dìde, mú aya rẹ ati àwọn ọmọ rẹ mejeeji tí wọ́n wà níhìn-ín kí o sì jáde, kí o má baà parun pẹlu ìlú yìí.” Ṣugbọn nígbà tí Lọti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ra, àwọn angẹli meji náà mú òun ati aya rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji, wọ́n kó wọn jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, nítorí pé OLUWA ṣàánú Lọti. Nígbà tí wọ́n kó wọn jáde tán, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín; ẹ má ṣe wo ẹ̀yìn rárá, ẹ má sì ṣe dúró níbikíbi ní àfonífojì yìí, ẹ sá gun orí òkè lọ, kí ẹ má baà parun.” Ṣugbọn Lọti wí fún wọn pé, “Áà! Rárá! oluwa mi. Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì kú. Ẹ wò ó, ìlú tí ó wà lọ́hùn-ún nì súnmọ́ tòsí tó láti sálọ, ó sì tún jẹ́ ìlú kékeré. Ẹ jẹ́ kí n sálọ sibẹ, ṣebí ìlú kékeré ni? Ẹ̀mí mi yóo sì là.” OLUWA dáhùn pé, “Ó dára, mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, n kò ní pa ìlú náà run. Ṣe kíá, kí o sálọ sibẹ, nítorí n kò lè ṣe ohunkohun, títí tí o óo fi dé ibẹ̀.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ìlú náà ní Soari. Oòrùn ti yọ nígbà tí Lọti dé Soari. OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora, ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀. Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Abrahamu lọ sí ibi tí ó ti dúró níwájú OLUWA, ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá. Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun. Nígbà tí ó yá, Lọti jáde kúrò ní Soari, nítorí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ibẹ̀, òun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji bá kó lọ sí orí òkè, wọ́n sì ń gbé inú ihò kan níbẹ̀. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò, ó ní, “Baba wa ń darúgbó lọ, kò sì sí ọkunrin kan tí yóo fẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn eniyan. Wò ó! Jẹ́ kí á mú baba wa mu ọtí àmupara, kí á sì sùn lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè bá wa lòpọ̀, kí á le tipasẹ̀ rẹ̀ bímọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún baba wọn ní ọtí mu ní alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àkọ́bí wọlé lọ, ó sì mú kí baba wọ́n bá òun lòpọ̀, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde. Ní ọjọ́ keji, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò pé, “Èmi ni mo sùn lọ́dọ̀ baba wa lánàá, jẹ́ kí á tún mú kí ó mu ọtí àmupara lálẹ́ òní, kí ìwọ náà lè wọlé tọ̀ ọ́ lọ, kí ó lè bá ọ lòpọ̀, kí á sì lè bímọ nípasẹ̀ baba wa.” Wọ́n mú kí baba wọn mu ọtí waini ní alẹ́ ọjọ́ náà pẹlu, èyí àbúrò lọ sùn tì í, baba wọn kò mọ ìgbà tí ó sùn ti òun, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ ìgbà tí ó dìde. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lọti mejeeji ṣe lóyún fún baba wọn. Èyí àkọ́bí bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Moabu, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Moabu títí di òní olónìí. Èyí àbúrò náà bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Bẹnami, òun ni baba ńlá àwọn ẹ̀yà Amoni títí di òní olónìí.

Gẹn 19:1-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní àṣálẹ́, àwọn angẹli méjì sì wá sí ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dìde láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sì foríbalẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.” Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.” Ṣùgbọ́n Lọti rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe àsè fún wọn, ó sì dín àkàrà aláìwú fún wọ́n, wọ́n sì jẹ. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Sodomu tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká. Wọ́n pe Lọti pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.” Lọti sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ìlẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde. Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe ṣe ohun búburú yìí, kíyèsi i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.” Wọ́n sì wí fún pé, “Bì sẹ́yìn fún wa. Èyí yìí wá ṣe àtìpó láàrín wa, òun sì fẹ́ ṣe onídàájọ́! Aburú tí a ó fi ṣe ọ́ yóò pọ̀ ju tí wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọti, wọ́n sì súnmọ́ ọn láti fọ́ ìlẹ̀kùn. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọti wọlé, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu-ọ̀nà mọ́. Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọti pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ́ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí, nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búburú wọn ń dí púpọ̀ níwájú OLúWA, OLúWA sì rán wa láti pa á run.” Nígbà náà ni Lọti jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí, nítorí OLúWA fẹ́ pa ìlú yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí OLúWA ṣàánú fún wọn. Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde sẹ́yìn odi tán, ọ̀kan nínú wọn wí pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀! Sá àsálà lọ sí orí òkè, kí ìwọ ó má ba ṣègbé!” Ṣùgbọ́n Lọti wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́! Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúrere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è sálọ sórí òkè, kí búburú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú. Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòsí láti sá sí: jẹ́ kí n sálọ síbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́? Ẹ̀mí mi yóò sì yè.” Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀. Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀,” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari). Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ. Nígbà náà ni OLúWA rọ̀jò iná àti Sulfuru (òkúta iná) sórí Sodomu àti Gomorra—láti ọ̀run lọ́dọ̀ OLúWA wá. Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Abrahamu sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú OLúWA. Ó sì wo ìhà Sodomu àti Gomorra àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru. Ọlọ́run sì rántí Abrahamu, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọti jáde kúrò láàrín ìparun náà, tí ó kọlu ìlú tí Lọti ti gbé. Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Soari, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Soari. Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbègbè yìí tí ìbá bá wa lòpọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé. Wá, jẹ́ kí a mú baba wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lòpọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.” Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lòpọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìde. Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti baba mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú-ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé sùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde. Àwọn ọmọbìnrin Lọti méjèèjì sì lóyún fún baba wọn. Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Moabu. Òun ni baba ńlá àwọn ará Moabu lónìí. Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bene-Ami. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ammoni lónìí.