Gẹn 18:23-24
Gẹn 18:23-24 Yoruba Bible (YCE)
Abrahamu bá súnmọ́ OLUWA, ó wí pé, “O ha gbọdọ̀ pa àwọn olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú bí? A kì í bàá mọ̀, bí aadọta olódodo bá wà ninu ìlú náà, ṣé o óo pa ìlú náà run, o kò sì ní dá a sí nítorí aadọta olódodo tí ó wà ninu rẹ̀?
Pín
Kà Gẹn 18Gẹn 18:23-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu? Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀?
Pín
Kà Gẹn 18Gẹn 18:23-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ OLúWA, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” “Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?
Pín
Kà Gẹn 18