Gẹn 18:1-2
Gẹn 18:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si farahàn a ni igbo Mamre: on si joko li ẹnu-ọ̀na agọ́ ni imõru ọjọ́: O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ.
Gẹn 18:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọ̀sán gangan ọjọ́ kan, OLUWA fara han Abrahamu bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, lẹ́bàá igi Oaku ti Mamure. Bí ó ti gbójú sókè, bẹ́ẹ̀ ni ó rí àwọn ọkunrin mẹta kan, wọ́n dúró ní ọ̀kánkán níwájú rẹ̀. Bí ó ti rí wọn, ó sáré lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ láti kí wọn.
Gẹn 18:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì farahan Abrahamu nítòsí àwọn igi ńlá Mamre, bí ó ti jókòó ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́-kanrí tí oòrùn sì mú. Abrahamu gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀. Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn.