Gẹn 17:6-11
Gẹn 17:6-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si mu ọ bí si i pupọpupọ, ọ̀pọ orilẹ-ède li emi o si mu ti ọdọ rẹ wá, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wá. Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lãrin temi tirẹ, ati lãrin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati ma ṣe Ọlọrun rẹ, ati ti irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ. Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn. Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Nitorina ki iwọ ki o ma pa majẹmu mi mọ́, iwọ, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn. Eyi ni majẹmu mi, ti ẹnyin o ma pamọ́ lãrin temi ti nyin, ati lãrin irú-ọmọ rẹ, lẹhin rẹ; gbogbo ọmọkunrin inu nyin li a o kọ ni ilà. Ẹnyin o si kọ ara nyin ni ilà; on ni yio si ṣe àmi majẹmu lãrin temi ti nyin.
Gẹn 17:6-11 Yoruba Bible (YCE)
N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.” “N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ. N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!” Ọlọrun tún sọ fún Abrahamu pé, “Ìwọ pàápàá gbọdọ̀ pa majẹmu mi mọ́, ìwọ ati atọmọdọmọ rẹ láti ìrandíran wọn. Majẹmu náà tí ó wà láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ, tí ẹ gbọdọ̀ pamọ́ nìyí, gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Ilà abẹ́ tí ẹ gbọdọ̀ kọ yìí ni yóo jẹ́ àmì majẹmu tí ó wà láàrin mi pẹlu yín.
Gẹn 17:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.” Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín.