Gẹn 16:1-2
Gẹn 16:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i OLúWA ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.” Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ.
Gẹn 16:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
SARAI, aya Abramu, kò bímọ fun u: ṣugbọn o li ọmọ-ọdọ kan obinrin, ara Egipti, orukọ ẹniti ijẹ Hagari. Sarai si wi fun Abramu pe, kiyesi i na, OLUWA dá mi duro lati bímọ: emi bẹ̀ ọ, wọle tọ̀ ọmọbinrin ọdọ mi; o le ṣepe bọya emi a ti ipasẹ rẹ̀ li ọmọ. Abramu si gbà ohùn Sarai gbọ́.

Gẹn 16:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Sarai, aya Abramu, kò bímọ fún un. Ṣugbọn ó ní ẹrubinrin ará Ijipti kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari. Ní ọjọ́ kan, Sarai pe Abramu, ó sọ fún un pé, “Ṣé o rí i pé OLUWA kò jẹ́ kí n bímọ, nítorí náà bá ẹrubinrin mi yìí lòpọ̀, ó le jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni n óo ti ní ọmọ.” Abramu sì gba ọ̀rọ̀ Sarai aya rẹ̀.