Gẹn 15:18-20
Gẹn 15:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate: Awọn enia Keni, ati awọn enia Kenissi, ati awọn enia Kadmoni, Ati awọn enia Hitti, ati awọn enia Perissi, ati awọn Refaimu
Gẹn 15:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate, ilẹ̀ àwọn ará Keni, ti àwọn ará Kenisi, ti àwọn ará Kadimoni, ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Refaimu
Gẹn 15:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà gan an ni OLúWA dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu.