Gẹn 15:15-18
Gẹn 15:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o si tọ̀ awọn baba rẹ lọ li alafia; li ogbologbo ọjọ́ li a o sin ọ. Ṣugbọn ni iran kẹrin, nwọn o si tun pada wá nihinyi: nitori ẹ̀ṣẹ awọn ara Amori kò ti ikún. O si ṣe nigbati õrùn wọ̀, òkunkun si ṣú, kiyesi i ileru elẽfin, ati iná fitila ti nkọja lãrin ẹ̀la wọnni. Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate
Gẹn 15:15-18 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ náà yóo dàgbà, o óo di arúgbó, ní ọjọ́ àtisùn rẹ, ikú wọ́ọ́rọ́wọ́ ni o óo kú. Atọmọdọmọ rẹ kẹrin ni yóo pada wá síhìn-ín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò tíì kún ojú òṣùnwọ̀n.” Nígbà tí oòrùn wọ̀, tí ilẹ̀ sì ṣú, kòkò iná tí ó ń rú èéfín ati ìtùfù tí ń jò lálá kan kọjá láàrin àwọn ẹran tí Abramu tò sílẹ̀. Ní ọjọ́ náà ni OLUWA bá a dá majẹmu, ó sọ pé, “Àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ijipti títí dé odò ńlá nì, àní odò Yufurate
Gẹn 15:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.” Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. Ní ọjọ́ náà gan an ni OLúWA dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate