Gẹn 15:1-6
Gẹn 15:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi ọ̀rọ OLUWA tọ̀ Abramu wá li ojuran, wipe, Má bẹ̀ru, Abramu; Emi li asà rẹ, ère nla rẹ gidigidi. Abramu si wipe, OLUWA Ọlọrun, kini iwọ o fi fun mi, emi sa nlọ li ailọmọ, Elieseri ti Damasku yi si ni ẹniti o ni ile mi? Abramu si wipe, Wo o emi ni iwọ kò fi irú-ọmọ fun: si wo o, ẹrú ti a bi ni ile mi ni yio jẹ arolé. Si wo o, ọ̀rọ OLUWA tọ̀ ọ wá, wipe, Eleyi ki yio ṣe arole rẹ; bikoṣe ẹniti yio ti inu ara rẹ jade, on ni yio ṣe arole rẹ. O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹ̃ni irú-ọmọ rẹ yio ri. O si gba OLUWA gbọ́; on si kà a si fun u li ododo.
Gẹn 15:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, OLUWA bá Abramu sọ̀rọ̀ lójú ìran, ó ní, “Má bẹ̀rù Abramu, n óo dáàbò bò ọ́, èrè rẹ yóo sì pọ̀ pupọ.” Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni? O kò fún mi lọ́mọ, ẹrú tí wọ́n bí ninu ilé mi ni yóo di àrólé mi!” OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe ọkunrin yìí ni yóo jẹ́ àrólé rẹ, ọmọ bíbí inú rẹ ni yóo jẹ́ àrólé rẹ.” OLUWA bá mú un jáde, ó sì sọ fún un pé, “Wo ojú ọ̀run, kí o ka gbogbo ìràwọ̀ tí ó wà níbẹ̀ bí o bá lè kà wọ́n.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo ṣe pọ̀ tó.” Abramu gba OLUWA gbọ́, OLUWA sì kà á sí olódodo.
Gẹn 15:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Abramu wá lójú ìran pé: “Abramu má ṣe bẹ̀rù, Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.” Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “OLúWA Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” OLúWA sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.” Abramu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.