Gẹn 14:8-12
Gẹn 14:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba Sodomu si jade, ati ọba Gomorra, ati ọba Adma, ati ọba Seboimu, ati ọba Bela, (eyini ni Soari;) nwọn si tẹgun si ara wọn li afonifoji Siddimu; Si Kedorlaomeri ọba Elamu, ati si Tidali ọba awọn orilẹ-ède, ati Amrafeli ọba Ṣinari, ati Arioku ọba Ellasari, ọba mẹrin si marun. Afonifoji Siddimu si jẹ kìki kòto ọ̀da-ilẹ; awọn ọba Sodomu ati ti Gomorra sá, nwọn si ṣubu nibẹ̀; awọn ti o si kù sálọ si ori oke. Nwọn si kó gbogbo ẹrù Sodomu on Gomorra ati gbogbo onjẹ wọn, nwọn si ba ti wọn lọ. Nwọn si mu Loti, ọmọ arakunrin Abramu, ti ngbé Sodomu, nwọn si kó ẹrù rẹ̀, nwọn si lọ.
Gẹn 14:8-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni ọba Sodomu, ati ọba Gomora jáde lọ, pẹlu ọba Adima, ọba Seboimu, ati ọba Bela, (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Wọ́n pa ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu. Wọ́n gbógun ti Kedorilaomeri, ọba Elamu, Tidali, ọba Goiimu, Amrafeli, ọba Babiloni ati Arioku, ọba Elasari. Ọba mẹrin dojú kọ ọba marun-un. Àfonífojì Sidimu kún fún ihò tí wọ́n ti wa ọ̀dà ilẹ̀. Bí àwọn ọmọ ogun ọba Sodomu ati àwọn ọmọ ogun ọba Gomora ti ń sálọ, àwọn kan ninu wọn jìn sinu àwọn ihò náà, àwọn yòókù sá gun orí òkè lọ. Àwọn ọ̀tá kó gbogbo ẹrù ati oúnjẹ àwọn ará Sodomu ati Gomora, wọ́n bá tiwọn lọ. Ọwọ́ wọn tẹ Lọti, ọmọ arakunrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu, wọ́n mú un lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ.
Gẹn 14:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Ṣeboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu, láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè. Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ. Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀.