Gẹn 13:5-18

Gẹn 13:5-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ati Loti pẹlu, ti o ba Abramu lọ, ni agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran, ati agọ́. Ilẹ na kò si le igbà wọn, ki nwọn ki o le igbé pọ̀: nitori ini wọn pọ̀, bẹ̃nì nwọn kò si le gbé pọ̀. Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na. Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe. Gbogbo ilẹ kọ́ eyi niwaju rẹ? emi bẹ̀ ọ, yà ara rẹ kuro lọdọ mi: bi iwọ ba pọ̀ si apa òsi, njẹ emi o pọ̀ si ọtún; tabi bi iwọ ba pọ̀ si apa ọtùn, njẹ emi o pọ̀ si òsi. Loti si gboju rẹ̀ si oke, o si wò gbogbo àgbegbe Jordani, pe o li omi nibi gbogbo, ki OLUWA ki o to pa Sodomu on Gomorra run, bi ọgbà OLUWA, bi ilẹ Egipti, bi iwọ ti mbọ̀wa si Soari. Nigbana ni Loti yàn gbogbo àgbegbe Jordani fun ara rẹ̀; Loti si nrìn lọ si ìha ìla-õrùn: bẹ̃ni nwọn yà ara wọn, ekini kuro lọdọ ekeji. Abramu si joko ni ilẹ Kenaani, Loti si joko ni ilu àgbegbe nì, o si pagọ́ rẹ̀ titi de Sodomu. Ṣugbọn awọn ọkunrin Sodomu ṣe enia buburu, ati ẹlẹṣẹ gidigidi niwaju OLUWA. OLUWA si wi fun Abramu, lẹhin igbati Loti yà kuro lọdọ rẹ̀ tan pe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò lati ibi ti o gbé wà nì lọ, si ìha ariwa, ati si ìha gusu, si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ìwọ-õrùn: Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai. Emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi erupẹ ilẹ: tobẹ̃ bi o ba ṣepe enia kan ba le kà iye erupẹ ilẹ, on li a o to le kaye irú-ọmọ rẹ pẹlu. Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun. Nigbana ni Abramu ṣí agọ́ rẹ̀, o si wá o si joko ni igbo Mamre, ti o wà ni Hebroni, o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA.

Gẹn 13:5-18 Yoruba Bible (YCE)

Lọti tí ó bá Abramu lọ náà ní ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo mààlúù ati ọpọlọpọ àgọ́ fún ìdílé rẹ̀ ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ẹran ọ̀sìn àwọn mejeeji pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ náà kò fi láàyè tó mọ́ fún wọn láti jọ máa gbé pọ̀. Ìjà sì ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn darandaran Abramu ati àwọn ti Lọti. Ní àkókò náà, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi ń gbé ilẹ̀ náà. Abramu bá sọ fún Lọti pé, “Má jẹ́ kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, tabi láàrin àwọn darandaran mi ati àwọn tìrẹ. Ṣebí ara kan náà ni wá? Ilẹ̀ ló lọ jaburata níwájú rẹ yìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí á takété sí ara wa. Bí o bá lọ sí apá òsì, èmi á lọ sí apá ọ̀tún, bí o bá sì lọ sí apá ọ̀tún, èmi á lọ sí apá òsì.” Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run. Lọti bá yan gbogbo agbègbè odò Jọdani fún ara rẹ̀, ó sì lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe takété sí ara wọn. Abramu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì ń gbé ààrin àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè odò Jọdani, ó pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. Àwọn ará Sodomu yìí jẹ́ eniyan burúkú, wọn ń dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí Lọti ti kúrò lọ́dọ̀ Abramu, OLUWA sọ fún Abramu pé, “Gbé ojú rẹ sókè, kí o wò ó láti ibi tí o wà yìí, títí lọ sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, tún wò ó lọ sí ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn. Gbogbo ilẹ̀ tí ò ń wò yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún títí lae. N óo mú kí àwọn ọmọ rẹ pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tí yóo fi jẹ́ pé, àfi ẹni tí ó bá lè ka iye erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóo lè kà wọ́n. Dìde, kí o rìn jákèjádò ilẹ̀ náà, nítorí pé ìwọ ni n óo fún.” Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA.

Gẹn 13:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà. Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.” Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà OLúWA, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí OLúWA tó pa Sodomu àti Gomorra run). Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè Àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú OLúWA. OLúWA sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.” Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún OLúWA.