Gẹn 13:1-4
Gẹn 13:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ABRAMU si goke lati Egipti wá, on, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ati Loti pẹlu rẹ̀, si ìha gusu. Abramu si là gidigidi, li ẹran-ọ̀sin, ni fadaka, ati ni wurà. O si nrìn ìrin rẹ̀ lati ìha gusu lọ titi o si fi de Beteli, de ibi ti agọ́ rẹ̀ ti wà ni iṣaju, lagbedemeji Beteli on Hai. Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA.
Gẹn 13:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde kúrò ní Ijipti, ó pada lọ sí Nẹgẹbu pẹlu aya rẹ̀, ati Lọti ati ohun gbogbo tí ó ní. Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ. Nígbà tí ó yá, ó kúrò ní Nẹgẹbu, ó ń lọ sí Bẹtẹli, ó dé ibi tí ó kọ́kọ́ pàgọ́ sí láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA.
Gẹn 13:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà. Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ OLúWA.